Home / Àṣà Oòduà / Idile Alayo: Oro owun si fe toju sumi

Idile Alayo: Oro owun si fe toju sumi

A ki gbogbo wa ku jimo oloyin toni a si ki wa ku abo sori eto Idile Alayo ti ose yi, gege bi ise wa atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara won ololufe eto yi ni a o maa ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won lamoran bi o ti ye. E gbo bi atejise na ti lo;-

“Olootu mo ki yin pupo o, e dakun olootu oro mi o po rara, emi ati baale mi ni a jo n se fanfa lori oro kan, oro owun si fe toju sumi, ni mo ni ki n fi to awon ojogbon eniyan leti ki won gba mi lamoran.

Eyin ojogbon ati onilakaye eto Idile Alayo e dakun e lami loye o, odun ikerinla ree ti mo ti wa nile oko, omo merin ni emi ati oko mi jo damoran lati bi, sugbon ni bayi Omo marun ni nbe lagbala wa, idi si ni wipe omo merin akoko ti Eledua fi ta wa loore obinrin ni gbogbo won, beeni oko mi nkigbe oun nilo Arole dandan ni, eyi ni o sun wa ni akarun, sugbon se eniyan o kuku gbon ju Aseda lo, iyalenu ni o je fun wa wipe obinrin ni omo ikarun ti a tun bi.

Beeni mo gba oko mi lamoran wipe ko si eni ti Eledua o le fi se arole, a saa ri idile ti okunrin wa toje obinrin ibe ni Eledua nlo fun ogo idile owun sugbon gbogbo atoto arere mi yi eyin eti oko mi ni o nbo si. Beeni oko mi wipe ti oun ko ba bi omo okunrin, oun ko ni dawo omo bibi duro! Koda mo bi oko mi wipe se ti a ba bi omo mewa ti ko si s’okunrin laarin won, se a o tesiwaju na ni? Beeni oko mi daun wipe ti eniyan ko ba de ibi ti nlo kii duro!

Oro yi wa n se mi ni kayefi tori emi o nife si ki eniyan bimo jo bi eku eda, looto oko mi a maa gbiyanju nipa itoju awon omo o koda kii fi oro awon omo re sere rara, sugbon mo ranti wipe maami a ma ki wa nilo lopo igba wipe omo ti obinrin ba le to ni ki o bi nitori ko si eni ti o mo ile ti yoo mo ni ola.

Nibi ti mo ti nparowa fun oko mi ni o ti na aba meji sile wipe kin mu okan ninu e, akoko ni wipe ki ntesiwaju lati maa bimo titi Eledua yoo fi fi omokunrin da wa lola tabi ki nyonda oun lati fe iyawo miran ki n mu okan nibe.

Oro yi wa so si mi lenu koda o bu iyo si tori nko fi iseju kan ninu ojo aye mi gbadura fun ile olorogun, koda mo korira ile olorogun ju nkan miran lo, nitori nko fe ki ohunkohun da isokan ti nbe ninu idile mi ru, nko si fe nkan ti yoo se akoba fun awon omo mi beeni nko fe tesiwaju lati maa bimo jo bi eku eda!

Iyen ni mo se ni ki nfi oro yi lo eyin ojogbon wipe ni ikorita ti mo wa yi ogbon wo ni a da sii, se ki nma bimo lo lati deni iyawo ikeji ni abi ki nyoda oko mi ki o se ife inu re, eyin ojogbon oro ree o, e jowo e la mi loye o!

Hmmmm oro loko-laya afi ka fi senu ka dake o! Ki ni a o ti se eyi si bayi, nje ti arabinrin yi ba ni anfani lati seda omo se ko kuku ni fi gbogbo omo re se okunrin bayi? Beeni o kuku ye oko iyawo pelu, abi nigba ti awon obinrin wonyi ba gba’le oko won lo lojo iwaju ta ni yoo ma ba alagba yi je oruko po? Eyin baba ati iya wa nile oro ree o, ewo ni ki arabinrin yi se gan bayi???

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo