Ìjọba Nàìjíríà kéde ìlànà tuntun fún ìséde Kofi-19
Ṣe àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní kò sí ohun kan tó le le le tí kìí padà rọ̀, ìdí nìyí tó fí jẹ́ pé, ìrọ́jú ló yẹ ẹni tí eégún bá ń lé…
Ìjọba Orílẹ̀ yìí ti fi ọjọ́ kún ìséde Kòrónáfairọ̀ọ̀sì jákèjádò Nàìjíríà.
Ní báyìí, dípò aago mẹ́wàá alẹ́ sí mẹ́rin ìdájí, aago méjìlá òru sí mẹ́rin ìdájí ni Ìṣéde yóó fi má a wà.
Ọgbọ̀nọ́njọ́, oṣù Kẹta, ọdún 2020 ni Ààrẹ kọ́kọ́ kéde Ìṣéde ní ìpínlẹ̀ Èkó, Ògùn àti ìlú Àbújá, níbi tí Kofi-19 ti kọ́kọ́ gbilẹ̀.
Alága Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá fún amójútó kòrónáfairọ̀ọ̀sì ní Nàìjíríà, Sani Mustapha, ló kéde àṣẹ tuntun yìí lọ́jọ́bọ.
Ó ṣàlàyé pé àǹfààní ti wà fún àwọn Ilé sinimá, ibùdó tí wọ́n ti ń se eré ìdárayá, àti àwọn ibùdó fàájì tó kù, láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà.
Bákan náà ló sọ pé kí àwọn ile ẹ̀kọ́ má a múra sílẹ̀ fún wíwọlé padà.
Musatpha sọ pé kọ́kọ́rọ́ kan tó ba eyín ajá jẹ́ ni àwọn tí kò tẹ̀lé Ìlànà Ìjọba fún àrùn Kofi-19.
Àwọn nǹkan tó tún wà nínú àṣẹ tuntun tí Ìjọba kéde
Àwọn ilé ìtura ti lè sí ìlẹ̀kùn wọn.
Ilé sinimá, ibi tí wọ́n ti ń ṣe eré ìdárayá le sí padà, ṣùgbọ́n èrò wọn kò gbọdọ̀ ju ìdá àádọ́ta lọ
Àwọn gbọ̀ngàn ayẹyẹ lè síi padà, ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ ju ìdá àádọ́ta lọ
Àwọn ilé oúnjẹ kò gbọdọ̀ gbà kí ẹnikẹ́ni jókòó jẹun lọ́ọ̀dọ wọn
Àwọn ilé ọtí àti ilé ijó kò gbọdọ̀ ṣí ìlẹ̀kùn
Àjọ NYSC yóó bẹ̀rẹ̀ ìmúra sílẹ̀ fún ìgbà tí àwọn ile ẹ̀kọ́ yóó di ṣíṣí padà
Àjọ INEC yóó ríi dájú pé ó tẹ̀lé Ìlànà lórí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì – ẹni tí kò bá lo ìbòmú kò gbọdọ̀ dìbò. Bákan náà ni wọn ó tún má a ṣe àyẹ̀wò bí ara àwọn èèyàn ṣe gbóná sí, lo sanitáísà, àti títakété síra ẹni.
Fẹ́mi Akínṣọlá