*Mimiko ya bilionu meedogun soto lati san gbese
Lose to koja ni awuyewuye kan tun seyo nipinle Ondo nigba ti egbe oselu APC tako Gomina Olusegun Mimiko ti ipinle naa nipa bo se ya bilionu meedogun ati milionu mejo (N15. 8b) soto lati san gbese nikan. Owo ti Mimiko ya soto yii lo jeyo ninu eto isuna owo ipinle naa fodun 2016.
Adari eto iroyin ati ipolongo fun egbe oselu APC, Ogbeni Steve Otaloro, lo tuto soke to si foju gbaa ninu atejade kan to fi sowo si awon oniroyin niluu Akure.
Ninu atejade naa lo ti bu enu ate lu ijoba Mimiko gege bi ijoba etan ati jaguda paali ti n fi owo mejeeji ko owo ilu mi bi kalokalo.
“Bawo ni ijoba yoo se ya N15.850b soto lati san gbese nikan, eleyii ti n se ida ogbon ninu ogorun (30%) owo isuna odun kan soso. Kosi tabisugbon ninu oro to wa nile yii, egbe PDP ti ta ojo ola ipinle Ondo danu,” Ogbeni Otaloro se alaye re bee.
Bakan naa ni Ogbeni Otaloro tun tenu mo wi pe, awon ise akanse ti Mimiko salaye ninu iwe eto isuna wi pe awon fe na aadota bilion ati milionu mesa-an (N50.9 b) le lori, lo je awon ise ti won ti yo owo re soto tele ni awon igba kan seyin.
Ogbeni Otaloro ko sai tun gbe orinkiniwin alaye re kale nipa bi ijoba PDP ti Mimiko ko sodi se ja awon eniyan ipinle Ondo ni jibiti tirilionu kan naira eleyii to je owo ti ipinle naa pa wole lati odun bi 2009.
Wayio, Ogbeni Otaloro ti gba Mimiko niyanju lati wo awokose Muhammadu Buhari, eleyii to je wi pe larija eto isuna owo re da lori ona lati mu aye derun fun awon mekunnu.