Home / Àṣà Oòduà / KÁDÀRÁ Ò GBÓÒGÙN

KÁDÀRÁ Ò GBÓÒGÙN

Adáni wáyé ti dáni sáyé ná.
Káwayé máyà tó sayé dàwáàlọ.
Òréré layé kò see wò tán.
Àyàfi ká gba kádàrá lókù.
Kádàrá ò seé kọ̀ láìgbà.
Ádíá f’ẹ́ja tó f’ibú selé.
Ádíá f’ọ́pọ̀lọ́ tó f’òkè s’ebùgbé.
Ọ̀pọ̀ló f’omi s’elé, ó fèèpẹ̀ s’ebùgbé.
Àdán s’ẹyẹ tán, ó tún s’eku.
Lọ́wọ́ ọba mi àrà tí ń sisẹ́ àràmàǹdà.
Kí gbogbo ẹyẹ ó máse bínú àdán mọ́.
Kí gbogbo ẹja ó máse bínú ọ̀pọ̀lọ́ gan.
Ìpín-ò-jọ̀pín nílé ayé ń bí.
K’óníkálukú gba ti ẹ̀ lókù.
Iná ń bẹ lábẹ́ asọ kóówá.
Bí ti ń jóníkálùkù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Iná tí ń jóni tá ò gbọdọ̀ jósí.
Iná tí ń jóni tá ò le è pa.
Iná abẹ́ asọ a máa jóni lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
Ẹ̀dá tí ń sáré àtilà.
Kó rántí ẹni tó sáré là tí ò tọ́jọ́.
Ẹ̀dá tí ń sáré àtilu.
Kó rántí ẹni tó sáré lura rẹ̀ mọ́lẹ̀.
Ẹni ọba mi òkè bá pá lórí kó dúpé.
Lọ́jọ́ tí wèrè bá mọlé onígbàjamọ̀.
Ẹkún ń lá, tí kò leè sun ni.
Olówó ń sunkún, ẹ̀yin lẹ ò gbọ́
Ẹdìẹ ń làágùn, ẹ̀yin le ò mọ̀.
Iná tí ń jóni lábẹ́ asọ.
S’ebí lára oníkálukú ní ń bẹ.
Iná tí ń jóni tá ò leè pa.
Iná abẹ́ asọ ni wọ́n pè bẹ́ẹ̀.
Bí ẹ r’ẹ́ni tó lówó lọ́wọ́ bí alówólódù,
Ẹ má rò pó ti ń dùn bí ìlù dùn-ùn dún.
Ohun tí ń rán lábẹ́ asọ rẹ̀ ń dùn-ún dénú.
Ènìyàn le lówó lọ́wọ́ láì l’ẹ́nìkan.
Ènìyàn le lówó lọ́wọ́ láì láya ńlé.
Débi wípé ó máa bímọ gan.
Obìnrin le lówó lọ́wọ́.
Obìnrin le lẹ́wà lọ́dọ̀,
Kó tún jẹ́ opó ọ̀sán gangan.
Lọ́wọ́ ọba mi àrà tí ń sisé àràmàǹdà.
Òbìrí layé ẹ̀yin ọ̀rẹ́.
Òbìrí layé ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ẹ̀ mi.
Ẹní lòrí ò ní fìlà.
Ẹni nì fìlà ò lórí.
Ẹni ra bàtà ò lẹ́sẹ̀.
Ẹní lẹ́sẹ̀ ò ra bàtà.
Oníkálukú abi ti ẹ lára.
Iná ń jó ògiri ò sá.
Òjò ń rọ̀ òrùlé téwọ́.
Sebí wọ́n gba kádàrá ni.
Ká gba kádàrá,
Káma jírẹ̀ẹ́bẹ̀,
Sọ́ẉọ́ ọba mi àrà tí ń sisẹ́ àràmàǹdà.
Kámá torí gbígbó ká pajá.
Kámá torí kíkàn ká pàgbò.
Kámá torí àwíjàre kítọ́ ó tán lẹ́nu.
Ẹni bá torí p’élé ayé burú,
Tó wá gbòrun alákeji lọ.
Ẹ báni bi wọ́n pé kin ni wọ́n fẹ́ bá pàdé níbẹ̀ẹ̀ẹ̀ẹ̀ẹ̀ẹ̀ẹ̀.

About Awo

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo