Home / Àṣà Oòduà / Kilode Ti Ogbeni Bukola Saraki Fi N Paro?: O paro Nile Ejo Tiribuna, O Tun Paro Fun Omo Naijeria

Kilode Ti Ogbeni Bukola Saraki Fi N Paro?: O paro Nile Ejo Tiribuna, O Tun Paro Fun Omo Naijeria


Ni ile Yorubawa, ti omo kekere ba n paro, awon agba gba wi pe iru omo naa le jale tabi ko ti maa jale.

Lara esun metala ti eka onidajo ti Code of Conduct Bureau, Code of Conduct Tribunal gbe siwaju nipa bi Bukola Saraki se ji owo Ipinle Kwara pamo si ile ifowopamo ile okeere nigba ti n se ijoba ipinle naa gege bi gomina.

Leyin iroyin to jade lori ate iroyin Olayemi Oniroyin lana nipa bi won se le Saraki lokuta nibi won ti n kirun yidi niluu Ilorin, aimoye ile ise iroyin kaakiri ile Naijeria ni won tun jeri si isele naa. Koda, ile ise iroyin Sahara Reporters ti gbe fidio isele naa jade. E le ka iroyin naa nibi:

Sugbon ohun to joniloju ni wi pe, Bukola Saraki ti tako iroyin to jade gege bi ohun to jina si otito. Saraki ni ohun to jo bee ko waye rara.

Sugbon ninu atejade mii eleyii ti gomina Ipinle Kwara, Abdulfatah Ahmed fi sita, eni ti ko si ni yidi ni akoko naa; gomina bu enu ate lu bi awon eniyan se n so okuta lu aare ile igbimo asofin agba ati Emir ti ilu Ilorin.

O ni ohun idoti ni, eleyii ti ko ye ko waye nibi awon eniyan ti fe josin fun Olorun.

Saraki ni awon eniyan ko so oun lokuta nigba ti gomina Abdulfatah Ahmed koro oju si bi awon eniyan se so Saraki lokuta nibi ijosin fun Olorun Oba.

Ogbeni Saraki n paro, ko si si ododo ninu gbogbo awijare re pata. Awon eniyan n pariwo “ole” “ole” “ole” won si n ju okuta ati omi inu ora lu omo baba oloye saaju ki awon osise alaabo re to gbe salo. Sibesibe, Saraki ni awon eniyan se rankadeede oun lasan ni ki se okuta ni won ju.

Bukola Saraki so niwaju igbimo onidajo Code of Conduct Tribunal wi pe oun o jebi esun ole jija ati aise ododo nipa akosile dukia re eleyii to niro ninu.

Ti awon esun ti won fi kan Saraki ni CCT ko ba tile dawa loju boya Saraki n paro ni, isele to sele lojo odun ileya ati atejade Saraki fi ye wa wi pe ogbologbo oniro ni

Orisun:

 

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Ìdíle Saraki àti ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dájọ́ ìpàdé

Lẹ́yìn tí Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara ti tẹ̀lé òfin tí wọ́n wo ohun ìní ìdílé Saraki èyí tí wọ́n ń pé ibẹ̀ ni Ilé Arúgbó ní ìlú Ilorin, ìpínlẹ̀ Kwara, gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kan nínú rẹ̀ ti wá gbà láti yanjú aáwọ̀ láì ti ọwọ́ Ilé ẹjọ́ bọ̀ ọ́ mọ́.