Home / Àṣà Oòduà / Mí ò ì pinnu lóri ìdíje Ààrẹ ọdún 2023-Tinubu

Mí ò ì pinnu lóri ìdíje Ààrẹ ọdún 2023-Tinubu

Mí ò ì pinnu lóri ìdíje Ààrẹ ọdún 2023-Tinubu

Báá ti ṣe làá wí, ẹnìkan kìí yan àna rẹ̀ lódì ni Yorùbá wí àsamọ̀ yìí ló díá fún bí asáájú ẹgbẹ́ òṣelú ẹgbẹ́ APC, Sẹ́nétọ̀ Bola Ahmed Tinubu tí ṣọ pé òun kò ti ṣe ìpinnu láti díje dupò Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dun 2023.

Èyí lòdì sí àwọn onírúurú ọ̀rọ̀ tó ti ń lọ nígboro tẹ́lẹ̀, Asiwáju ní nǹkan tó jẹ òun lógún jùlọ ni bí ọrọ̀ ajé tó ń dẹnu kọlẹ̀ yìí yóò ṣe gbéra sọ padà àti bí ètò ìlera yóò ṣe padà bọ̀ sípò ní Nàìjíríà.

Tinubu sọ èyí di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fọwọ́ sí lọ́sàn sátide, èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tí yóò fọhùn láti ìgbà tí wọ́n ti yọ ọwọ́ Adams Oshiomhole láwo gẹ́gẹ́ bí alága ẹgbẹ́ náà tí wọ́n sì tú ìgbìmọ amúṣẹ́ṣe ká lọ́jọ́rú ọ̀ṣẹ̀ yìí.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó ní : Sí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti ń kùn pé ìgbésẹ̀ Ààrẹ Buhari àti ìpáde àwọn ìgbìmọ tuntun nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe é ṣe láti fi òpin sí ìpinnu mí láti di Ààrẹ Orílẹ̀ yìí lọ́dún 2023, ó ṣe mí láànú fún yín”

“Ènìyan ẹlẹ́ràn ara lásán ni mí tí kò sì ní òye ọjọ́ iwájú tàbí ọgbọ́n òṣèlú tí ẹ ń fi ẹnu pè yii, ẹ tí ń yọ ayọ̀ lórí ìpinnu ìjákulẹ̀ oyé Ààrẹ tí kò ti wáye rárá.

“Tinubu ní kìí ṣe irú àsìkò tí àrun Kofi–19 ń da ètò ọrọ̀ ajé láàmú yìí, mí ò rí ọjọ́ ìwájú tó bi ẹ̀yin ‘se ríi” Mí ò sì tíì ṣe ìpinnu kankan láti dupò Ààrẹ lọ́dún 2023 nítorí pé àwọn nǹkan tó ń kojú wa ní àsìkò yìí tí lágbára tó.

Ní àsìkò tí a wà yìí, mí ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ òṣèlú nípa ọdún 2023 jẹ mí lógún, mó rí èyí bí nǹkan tí kò bójú mu rárá, ó sì jẹ́ ìwà àìní ìmọ̀lára lásìkò ti ọ̀pọ̀ ń kojú ìṣòro oníhà méjì, ètò ọrọ̀ ajé tó nira àti àrùn tó ń kó ìkàyà bá gbogbo ayé.

Láti bí oṣù díẹ̀ sẹ́yìn ni mo ti ń ro àwọn ìlànà ìjọba tí a lè gbé sílẹ̀ tí yóò ràn ìjọba lọ́wọ́ níhìn àti lọ́hùn.

Ààrẹ tí sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tó sì sọ náà ni abẹ́ gé

Nítori idí èyí mo rọ gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá tí wọ́n túká àti gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ tókù láti fiyè dénú kí wọ́n sì máá wo ọjọ́ iwájú rere tó wà níwájú

Mó ti fara ṣiṣẹ́ fún ẹgbẹ́ bí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó kù tàbi jù ẹlòmíràn lọ, sùgbọ́n síbẹ̀ kò nimí lára láti túbọ̀ farajì gẹ́gẹ́ bi olórí, kò sì sí ẹni tó yẹ kó ní ìṣoro kankan lòdì sí èyí.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Tinubu, má dàá sí ọ̀rọ̀ ìdìbò gómìnà Edo–PDP kìlọ̀

Tinubu, má dàá sí ọ̀rọ̀ ìdìbò gómìnà Edo–PDP kìlọ̀ Ṣé látàrí a á sìnlú a à sìnlú yìí náà lọ̀rọ̀ wá di fàá ká já a báyìí, tí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ń jùkò ọ̀rọ̀ lu ra wọn.Nífèsì padà sí n tí aṣíwájú Tinubu ṣọ , ẹgbẹ́ òṣèlú “Peoples Democratic Party,PDP ” náà tí fèsì padà fún Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu lórí fídíò tó ti ní kí àwọn èèyàn Edo má ṣe dìbò fún Godwin Obaseki. Gómìnà Godwin Obaseki ni olùdíje ...