Home / Àṣà Oòduà / Naira Marley ń rìn ní bèbè ẹ̀wọ̀n lọ́dún 2020 bí kò bá fara hàn lórí ẹ̀sùn ìjọ́kọ̀gbé – Ilé ẹjọ́

Naira Marley ń rìn ní bèbè ẹ̀wọ̀n lọ́dún 2020 bí kò bá fara hàn lórí ẹ̀sùn ìjọ́kọ̀gbé – Ilé ẹjọ́

Naira Marley ń rìn ní bèbè ẹ̀wọ̀n lọ́dún 2020 bí kò bá fara hàn lórí ẹ̀sùn ìjọ́kọ̀gbé…..Ilé ẹjọ́

Àdúrà ká má rẹ́jọ́ loníkálukú ń gbà,kí èṣù ó sì má yá wa lò.Ṣùgbọ́n bí nǹkan ṣe ń lọ yìí fún Naira Marley, gbajúgbajà olórin tàkasúféè tí ìràwọ̀ rẹ̀ ń tàn lọ́wọ́ báyìí , àfàìmọ̀ kí ó má bẹ̀rẹ̀ ọdún 2020 pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n.

Ilé ẹjọ́ Májísírètì àgbà kan lágbègbè Tinubu nípìńlẹ̀ Èkó ló pàṣẹ pé bí Naira Marley tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Azeez Fashọla, kò bá fi ara hàn níwájú kóòtù náà ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kínní ọdún 2020, ẹ̀wọ̀n ló fi ń ṣeré.

Naira Marley ń jẹ́jọ́ ìjọ́kọ̀gbé níwájú Adájọ́ májísírètì Tajudeen Elias pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀, Idris Fashola, babatunde Fashola àti Kunle Obere.

Adájọ́ náà kìlọ̀ fún gbajúgbajà olórin náà láti fara hàn ní ọjọ́ náà , bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àṣẹ ẹ lọ gbé e wá ní wíwọ́ ní dídè (Bench warrant) lòun yóó pa fáwọn agbófinró lórí rẹ̀.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ilé ẹjọ́ pàṣẹ náà níbi ìtẹ̀síwájú ìgbẹ́jọ́ ẹ̀sùn jíjí ọkọ̀ gbé tí wọ́n fi kàn án.

Ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kejìlá ọdún 2019 ni wọ́n kọ́kọ́ gbé wọn lọ síwájú Ilé ẹjọ́ náà, ṣùgbọ́n Naira Marley kò yọjú sílé ẹjọ́.

Ní ọjọ́ náà, àwọn afurasí mẹ́ta tókù ní àwọn kò jẹ̀bi ọ̀rọ̀ ẹ̀sùn náà.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

ÌKéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ ÌJẹ̀ṣà

Ìkéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà

Ní ìtẹ̀síwájú orò ìwúyè Ọwá Obòkun Àdìmúlà ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, Ọwá Clement Adésuyì Haastrup, wọ́n ti kéde ìṣéde jákèjádò ìlú Iléṣà. Gẹ́gẹ́ bí Olóyè Àgbà Ọlálékan Fọ́lọ́runṣọ́ tí wọ́n jẹ́ Loro ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ṣe kéde, ìṣéde náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́jọ alẹ́ òní Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ kọkànlá títí di aago mẹ́fà Òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹrin (8pm of April 11 to 6am of April 12, 2025) Kí eku ilé ó gbọ́, kó sọ fún toko o!!! Gbogbo ènìyàn ...