Ile ise ijoba ipinle Ogun ti pe akiyesi awon ara ilu si iroyin eleje kan ti iwe iroyin kan gbe jade wi pe wahala wa laaarin awon oloja ti won gbe ni agbegbe Akute ati gomina ipinle Ogun, Senato Ibikunle Amosun. Iwe Iroyin to jade naa tun fi kun un wi pe atunse awon oju ona lati Akute titi to fi de Alagbole to wa ni ijoba ibile Ifo ti n lo lowo lo je ise owo awon egbe oloja eleyii ti won ni ijoba Amosun ko lati ba won dasi.
Gege bi atejade ti akowe agba fun ile ise ijoba ti n risi ise ode ati igbayegbadun ara ilu, Engr. Kayode Ademolake fi sita lojo Aje to koja yii se so. O salaye wi pe ohun to foju han gbangban ni wi pe ijoba ipinle Ogun ti gbe ise oju ona Sango-Ijoko-Agbole-Akute-Ojodu Abiodun, eleyii to wa lara oju ona ti won soro ba, fun awon agbase se.
Ogbeni Kayode lo je ohun ijoloju lati gbo wi pe awon kan an pa iru iro bantabatan bee wi pe kii se ijoba lo n se awon ise oju ona naa. “Ko ni dara ki a maa da idagbasoke ilu po mo oselu sise, idagbasoke ye ko je ojuse gbogbo wa ni”. Ogbeni Kayode tun soro siwaju sii…
“Bi o tile je wi pe awon ise naa fa seyin lenu ojo meta yii latari awon ojo suuru ti n ro, sibesibe eyi ko fi ibi kankan mu adiku de ba ileri ati ife gomina si awon ara ilu. Ohun to tun daju ni wi pe ijoba to wa lode yii ko ni loju orun ayafi ti o ba mu awon ileri re pata se. Pataki ibe ti mo tun gbodo fi kun ni wi pe aimoye ise lo wa lowo wa ti a n ba lo lati ri wi pe awon oju ona wa se e gba fun awon eniyan wa pelu irorun. Lara awon oju ona ti ise ti n tesiwaju ni oju ona Sango-Ijoko, Ope-Ilu, Agbado, Abule Ekun, Akute- Alagbole, Owode-Ijako eleyii towa laaarin oju ona Eko si Abeokuta, Sagamu-Ogijo, Ijebu Ode ati bee bee lo