Home / Àṣà Oòduà / Nítorí Àrùn Coronavirus Ìjọba Àpapọ̀ Ní Káwọn Arìnrìnàjò Láti Orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà, Gẹ̀ẹ́sì, Faransé Àtorilẹ̀èdè Mọ́kànlá Míràn O Gbélé Wọn

Nítorí Àrùn Coronavirus Ìjọba Àpapọ̀ Ní Káwọn Arìnrìnàjò Láti Orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà, Gẹ̀ẹ́sì, Faransé Àtorilẹ̀èdè Mọ́kànlá Míràn O Gbélé Wọn

Ṣé àwọn àgbà ní ogun tí yóó wọlé kóni, ọ̀nà là á ti í pàdé ẹ.
Gẹ́gẹ́ bíi ara ètò láti tètè rawọ́ ọwọ́jà àrùn apini ní mímí èémí Coronavirus wọlé, Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti gbẹ́sẹ̀lé ìrìnàjò láti àwọn orílẹ̀-èdè Mẹ́tàlá kan wọ orílẹ̀-èdè Naijiria.

Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé kò sí àwọn arìnrìnàjò láti àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́tàlá náà tó gbọdọ̀ wọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Àwọn orílẹ̀-èdè tí ọ̀rọ̀ kàn ni orílẹ̀-èdè China, Italy, Iran, South Korea, Spain, Japan, Faranse, Germany, Amẹrika, Norway, ilẹ Gẹẹsi, Netherlands ati orilẹede Switzerland.

Ìjọba àpapọ̀ ní àwọn gbé ìgbésẹ̀ yìí lórí àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ wí pé iye àwọn èèyàn tó ti fara kó àrùn Coronavirus ti ju ẹgbẹ̀rún kan lọ.

China 82007
Italy 27980
Iran 16169
South Korea, 8320
Spain 11178
Japan 829
Faranse 6573
Germany 6012
Amẹrika 3536
Norway 1169
ilẹ Gẹẹsi 1954
Netherlands 1705
Switzerland 2650
Alága ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá tí Ìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ̀ lórí pípalẹ̀mọ́ àrùn Coronavirus kúrò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà (Presidential Task Force on COVlD-19) ṣàlàyé fáwọn oníròyìn nílùúu Abuja pé àyẹ̀wò tó múnádóko yóó máa wáyé fún gbogbo àwọn èèyàn tó bá wọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lẹ́yìn àbẹ̀wò sáwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí; tí wọn yóó sì fi wọ́n sínú àhámọ́ ìyàsọ́tọ̀ àti àyẹ̀wò fún ọjọ́ mẹ́rìnlà.

Bákan náà ni Ìjọba àpapọ̀ tún ṣàlàyé pé àṣẹ yìí ló bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Sátidé, ọjọ́ kọkànlélọ́gún oṣù kẹta ọdún 2020.

Bákan náà ni wọ́n tún fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, lásìkò tí àṣẹ yìí yóó fi fìdí múlẹ̀, kò ní sí ààyè à ń fún ẹnikẹ́ni ní ìwé àṣẹ ìwọ̀lú-gbélùú tí a mọ̀ sí físà.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

ÌKéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ ÌJẹ̀ṣà

Ìkéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà

Ní ìtẹ̀síwájú orò ìwúyè Ọwá Obòkun Àdìmúlà ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, Ọwá Clement Adésuyì Haastrup, wọ́n ti kéde ìṣéde jákèjádò ìlú Iléṣà. Gẹ́gẹ́ bí Olóyè Àgbà Ọlálékan Fọ́lọ́runṣọ́ tí wọ́n jẹ́ Loro ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ṣe kéde, ìṣéde náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́jọ alẹ́ òní Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ kọkànlá títí di aago mẹ́fà Òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹrin (8pm of April 11 to 6am of April 12, 2025) Kí eku ilé ó gbọ́, kó sọ fún toko o!!! Gbogbo ènìyàn ...