Home / Àṣà Oòduà / Odu ifa IROSUN ATAPO – Faniyi David Osagbami

Odu ifa IROSUN ATAPO – Faniyi David Osagbami

 |    |
 |    |
| |  |
| | | |

 

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, bi a se njade lo laaro yi pelu ayo ati alaafia a koni pada sile pelu ibanuje o ase.
Odu ifa IROSUN ATAPO lo gate laaro yi, ifa yi fore fun akapo ti odu ifa yi ba jade si, ifa ni inu ise ati iya ni akapo yi wa sugbon ifa ni oun yio mu kuro nibe oun yio si mulo sinu oro, sugbon ifa yi kilo gidigidi fun akapo yi ki o mase silekun aseju leyin ti aye re bati wa dara tan ti o ti ni laari ki o ma baa pada sinu osi ati iya to wa tele.

 
Ifa naa ki bayi wipe: Orunmila ni gbongbo ta gongo dina a difa fun olobahun lojo ti o nbe ninu ise oun iya ijahanjahan igi oko ti won ni ki o karale ebo ni ki o wa se ki o baa le kuro ninu Iya to ngbe ki o ba le di olowo oloro sugbon won kin nilo wipe ti o bati di olowo oloro tan ki o mase silekun aseju o olobahun loun ti gbo , obi meji, eyele funfun, ekuru funfun, adiye funfun, otin olobahun rubo won si se sise ifa fun ko pe ko jina seni olobahun ba ara re ninu ile nla tokun fun gbogbo nkan meremere inu olobahun dun olobahun dolowo o doloro, selo di bi ojo melo kan sii seni olobahun ri lekun kan ninu ile to wa yen olobahun wa ndaro wipe ti oun ba silekun yi bayi boya oun a tie tun di oloro ju bayi lo seni olobahun lo silekun nigbati o maa wonu yara naa selo ba opolopo nkan meremere ile aye nibe to tun poju ti ibiti o wa tele lo o wa nwo OLOKUN to joko soju Omi, OLOKUN wa sope olobahun! Sebi won kilo fun e wipe ki o mase silekun aseju, olobahun wa bere sini be OLOKUN wipe ki o ma binu soun OLOKUN ba gba ipe olobahun o si lo olobahun wa bere aye iwo re jije o ni gbogbo oro ile aye patapata, ko tun pe ti olobahun tun ri lekun miran ninu yara to wa yen, bo se tun da ngbimoran niyen wipe ah! Oun tun maa silekun yi o oni inu Ibe gan ni oro ile aye maa pin si, bi olobahun se silekun niyen o to maa wole sinu yara bayi se lo ba ara re ninu apalapolo igi oko ti ibe se kiki idoti ati egbin pelu ijahanjanhan isepe igi olobahun bere sini da ara re lebi bi olobahun se pada sinu osi ayeraye niyen o, o wa bere sini nyin babalawo re layin sodi nje ko pe ko jina eyin ko wa rifa ojohun bo ti nse ifa de alase ebora abise ope abise wara.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe eledumare yio muwa kuro ninu ise ayeraye yio muwa wonu oro, ori wa yio gbewa dele olokun seni ade, ako ni siwawu ojukokoro ati aigbonran koni muwa pada sinu osi ayeraye o, eti wa koni di si ibawi o aaaseee.

 

 

English Version:

Good morning my people, how was your night? Hope it was fantastic, I pray as we are going out this morning with peace and joy, we shall not return back home with sadness ase.
It is IROSUN ATAPO corpus that revealed this morning, ifa foresee goodness for whoever this corpus revealed out for, ifa said this person will be take out of suffering life and put him/her in a good and treasury abode, ifa also warn this person not to misbehave whenever he/she is living fine so that he/she won’t go back into his/her wretch life.
Hear what the corpus said: Orunmila said the root spread buckled on the road it cast divined for tortoise when he was advised not to open a misbehaving door, this tortoise was living in poverty then and he was asked to offer sacrifice so that he could excel and became rich but he was warned not to misbehave when he become rich, two kola nuts, White hen, white pigeon, ekuru funfun, gin and he complied, suddenly tortoise just saw himself in a beautiful place that full up of treasure and he was so happy and started enjoying, when it was some days he found out there is another door inside the beautiful place that he was living and he was meditating that if he could open the door maybe he would be more wealthy than this, so he opened the door and he entered there and he found plenty things that is more than where he was living and he saw “OLOKUN” sitting on the top of ocean saying tortoise! And you have been warned not to open a misbehaving door, tortoise begged her not to be angry with him and OLOKUN accepted and she went away tortoise became rich plentifully he started enjoying a great life, in a few days he found another door in the treasury room and he also meditating as before that this place would be a very great place than where he has been living so far, tortoise had forgotten the warnings he opened the door again when he will entered the room he found himself in a corner of tree that full of dirty and dried stems of tree than where he was living when he was still wretched, tortoise was started blaming himself, this is how covetousness and misbehaving led tortoise back to wretched life.
My people, I pray this morning that God will take us from wretch home to treasury home, our head will lead us to house of OLOKUN and we shall never misbehave to return back to wretched life, our ears will never block to warnings ase.
ABORU ABOYE OOO.

 

Faniyi David Osagbami

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

ifa

Kùtùkùtù Ìrèní Laó He Erè Nígbódù Oòni

Òní laó roko létí opónÒla laó sákà lágbèrùKùtùkùtù ìrèní laó he erè nígbódù oòniKáyáa múlé pontíKámú òdèdè rokàKáfi agbada dínranÀwèje wèmu nípón omodé wòyí lójúÒrìsà lópabuké tánLódákún sábaro nídìíOmo-ojo húnsáré gíríjo-gíríjoOmo-ojo húnsáré gìrìjo-gìrìjoIlé-ifón kògba obàtáláÈlàgboro kògba òrìsàOjúgboro ni tàfínÈlàgboro ni tòrìsàOmi níti ojú-omi rúwáÈròyà wáàponÈròyà wáàmuRúkú-rùkù-rúkú niwón nse lókè ohùnkòErú kùnrin won nííjé bánakúErú bìnrin won nííjé wòrúkúDimúdimù aleìgbòOkùnrin yàkàwú orí ìgbáÌgbá kòwóOkùnrin yàkàwú kòsòkalèÒní laóko igbó olú-kóókó-bojoÒla laóko igbó olú-kóókó-bojoAkogbó olú-kóókó-bojo tánApa ekùn kan mìnììjò-miniijo tínbe lábé ìtíWónní kí ...