Home / Àṣà Oòduà / Odu Ifa Irosun Meji

Odu Ifa Irosun Meji

 |    |
 |    |
| | | |
| | | |

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, gbogbo ojo aye wa yio maa dara si lojojumo ni o ase.
Odu ifa IROSUN MEJI lo gate laaro yi, ifa yi gba akapo ti odu ifa yi ba jade si niyanju wipe ki o se etutu daradara nitori ona ire gbogbo to di moo ki o baa le la, ifa sope esu odara lo joko soju ona ire re ti ise re tabi òwò re kofi ni ilosiwaju rara, ifa ni to bati rubo oni ona re yio la yio si di olowo laye o.
Ifa naa ki bayi wipe:

Lokiloki logbadori a difa fun eleko idere lojo ti esu odara joko soju ona ire re ti oja re si kuta, eleko idere ba mu eeji kun eeta o gboko alawo lo won wa ko oke iponri ru won so ao rifa kan meji irosun meji lo hu jade, ni won ba sofun eleko idere wipe esu odara lo joko soju ona ire re ti ko jeki oja re ta, won wa ni ebo de ko ru oni ki won maa yan ohun lebo, won ni obi meji,………………igba ewe ayajo ifa) eleko idere kabomora o rubo won si se sise ifa fun esu odara si gbebo re, esu odara wa dide loju ona ire eleko idere o wa bere sini npolowo re fun awon ero to nlo to nbo wipe e wa yori oooo, bi awon eniyan se bere sini npebo eleko idere niyen o ti oja re bere sini nta gidigidi eleko idere wa di olowo o di olokun o di onide o wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.

Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe esu odara yio dide loju ona ire wa to joko si loni ire gbogbo yio wole de funwa, ise wa tabi owo wa koni kuta ao ni se lasan, esu odara omo agbode jifa yio polowo ise ati owo wa lo sode loni ogunlogo awon eniyan gidi yio si maa gbe ise to lowo lori funwa se o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.
TEST/IDANWO RANPE.
1. What is best topic to give this passage( oruko wo lo daraju lati fun ayoka yi)?
2. How many parts did esu odara took in this passage(ipa melo ni esu odara ko ninu ayoka yi)?

English Version: 

Continue After The Page Break

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

ifa

Kùtùkùtù Ìrèní Laó He Erè Nígbódù Oòni

Òní laó roko létí opónÒla laó sákà lágbèrùKùtùkùtù ìrèní laó he erè nígbódù oòniKáyáa múlé pontíKámú òdèdè rokàKáfi agbada dínranÀwèje wèmu nípón omodé wòyí lójúÒrìsà lópabuké tánLódákún sábaro nídìíOmo-ojo húnsáré gíríjo-gíríjoOmo-ojo húnsáré gìrìjo-gìrìjoIlé-ifón kògba obàtáláÈlàgboro kògba òrìsàOjúgboro ni tàfínÈlàgboro ni tòrìsàOmi níti ojú-omi rúwáÈròyà wáàponÈròyà wáàmuRúkú-rùkù-rúkú niwón nse lókè ohùnkòErú kùnrin won nííjé bánakúErú bìnrin won nííjé wòrúkúDimúdimù aleìgbòOkùnrin yàkàwú orí ìgbáÌgbá kòwóOkùnrin yàkàwú kòsòkalèÒní laóko igbó olú-kóókó-bojoÒla laóko igbó olú-kóókó-bojoAkogbó olú-kóókó-bojo tánApa ekùn kan mìnììjò-miniijo tínbe lábé ìtíWónní kí ...