Don't Miss
Home / Àṣà Oòduà / Odu ifa OTUA MEJI

Odu ifa OTUA MEJI

  |    |
| | | |
|   |
|   |

 

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, eledumare yio wa pelu wa o ase.
Odu ifa OTUA MEJI lo gate laaro yi, ifa yi gba akapo ti odu ifa yi ba jade si niyanju wipe ki o rubo enu re daradara nitori ki o ma baa fi enu ara re ba igbesi aye re je o, ki o ko enu re nijanu gidigidi, ki o si bo enu naa, ifa loun koni jeki omo araye tibi enu mu o ase.
Ifa naa ki bayi wipe:
Ayoro enu
Ayoro enu
Ebiti enu ko tase a difa fun oforo eyiti yio yin eyin meji toni ile oun kun tetete, won ni ki oforo rubo nitori ki o ma baa fi enu ara re ba igbesi aye re je(obi…………ewe ifa) sugbon o koti ogboin sebo, ti o ba wa ti di aaro nigbati awon agbe otu ife bati nlo si oko oforo yio duro seba oju ona yio maa paruwo wipe ile oun kun tetete, ile oun kun tetete, se lo wa di ojo kan ti baba agbe kan nbo lati oko o wa pinnu lati ya wo ibiti oforo ti maa npolongo ara re wipe ile oun kun tetete nigbati baba agbe yi maa debe o ri eye oforo yi to fo jade ninu ile re, nigbati baba maa wo inu ile naa eyin meji pere ni o ba nibe, inu bi baba agbe yi gidi wipe se nkan ti oforo yin ni eleyi to wa nparuwo wipe ile oun kun tetete, bi baba se fo eyin meji naa danu niyen, bi aye oforo se baje patapata niyen o ti o fi enu re ba igbesi aye re je, won ni kan maa tufada won ni won ko ki ntufada mo alawo ni yio maa yin ifa, ifa ni yio maa yin eledumare nje ko pe ko jina eyin ko ri ifa ojoun bo se nse.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe omo araye koni pa omo wa mowa loju nitori oro enu wa o, ako ni fi enu arawa koba ara wa o, igbesi aye wa koni baje nipa oro siso lase eledumare aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

 

English Version:

Good morning my people, how was your night? Hope it was great, may God be with us today ase.
It is OTUA MEJI CORPUS that revealed this morning, ifa advised whoever this corpus revealed out for that he/she should be keeping a secret he/she should not be talkative so that he/she will not use his/her mouth to destroy his/her life.
Hear what the Corpus said:
Ayoro enu
Ayoro enu
Ebiti enu ko tase it cast divined for oforo bird when she laid two eggs and proclaiming that her house was full of eggs, she was advised to offer sacrifice o that she will not use her own mouth to destroy her life(two kola nuts…………..) but she refused, whenever it is morning that farmers were going to the farm she will be proclaiming that her house was full of eggs, one day when one farmer was coming from farm he decided to check the house of oforo to see how her house was full of eggs, when the farmer reached the house of oforo, oforo flew away and the farmer found only two eggs in oforo’s nest and he was angry that is this what oforo was proclaiming that her house was full of eggs, a farmer immediately brake the two eggs and the life of oforo was destroyed.
My people, I pray this morning that we shall never use our mouths to destroying our life, we will never kill our child/children by our mouths and enemies will never break our eggs ase

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

ifa

Kùtùkùtù Ìrèní Laó He Erè Nígbódù Oòni

Òní laó roko létí opónÒla laó sákà lágbèrùKùtùkùtù ìrèní laó he erè nígbódù oòniKáyáa múlé pontíKámú òdèdè rokàKáfi agbada dínranÀwèje wèmu nípón omodé wòyí lójúÒrìsà lópabuké tánLódákún sábaro nídìíOmo-ojo húnsáré gíríjo-gíríjoOmo-ojo húnsáré gìrìjo-gìrìjoIlé-ifón kògba obàtáláÈlàgboro kògba òrìsàOjúgboro ni tàfínÈlàgboro ni tòrìsàOmi níti ojú-omi rúwáÈròyà wáàponÈròyà wáàmuRúkú-rùkù-rúkú niwón nse lókè ohùnkòErú kùnrin won nííjé bánakúErú bìnrin won nííjé wòrúkúDimúdimù aleìgbòOkùnrin yàkàwú orí ìgbáÌgbá kòwóOkùnrin yàkàwú kòsòkalèÒní laóko igbó olú-kóókó-bojoÒla laóko igbó olú-kóókó-bojoAkogbó olú-kóókó-bojo tánApa ekùn kan mìnììjò-miniijo tínbe lábé ìtíWónní kí ...