Odù kan gorí àtẹ,Ọdẹ́gbèmí Ọdẹ́gbolá11 goróyè Àràbà nílẹ̀ẹ̀bàdàn
Fẹ́mi Akínṣọlá
Erin wo! Àràbà Awo ilẹ̀ Ìbàdàn, Ògbó Awo Oyewusi Amọo Fakayode wọ káàl’ẹ̀ sùn.Ọjọ́ a kú là á dère,èèyàn ò sunwọ̀n láàyè. Bí àlá ló ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹni ọ̀rọ̀ kàn nílànà ìṣẹ̀ṣe nígbà tí wọ́n gbọ pé àgbà awo náà tí jawàá lẹ̀.
Ògbó awo Oyewusi ni Àràbà kẹrìnlélógún nínú ìtàn oyè gbogbo gbòò fún onísẹ̀ṣe nílẹ̀ẹ̀bàdàn.
Àràbà tí ó gbésẹ̀ yìí,gorí oyè ní ọdún 2013,nígbà tó fàdàgbá ayé rọ̀ ní ọjọ́kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2019.
Nínú ọkàn ò jọ̀kan ọ̀rọ̀ tí wọ́n fí ń ròyìn Àgbà awo náà, wọ́n fìwà rere, tíí ṣe ẹ̀sọ́ ọmọnìyàn ròyìn Ògbó awo Oyewusi Amọo nínú ìṣe rẹ̀ ní dúníyàn.
Olóyè náà ní wọ́n ní kò fẹ́ ìrẹ́jẹ fún ẹnikẹ́ni, kìí sì gbè sẹ́yìn àbòsí, bẹ́ẹ̀ ló kórìíra tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun.
Àgbà awo Fakayode wá ìrẹ́pọ̀ tó gbọngbọ́n láàrin àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ́ àti Ògbó awo nílẹ̀ẹ̀bàdàn àti àwọn ìlú mìíràn tó yíiká, èyí náà ló sì jẹ́ ó rọrùn tí ìdàgbàsókè fi bá ẹgbẹ́ onísẹ̀ṣe lásìkò o tiẹ̀ .
Ṣé orí tí yóó dádé,inú agogo idẹ ní tií wà, ọrùn tí yóó lèjígbà ìlẹ̀kẹ̀,inú agogo idẹ ní tií wá, ìbàdì tí yóó lo Mọ́sàajì,aṣọ ọba tíí taná yanran yanran inú agogo idẹ náà ní tií wá.
Bí Àràbà se gbésẹ̀ yìí, àwọn ìgbìmọ onísẹ̀ṣe lápapọ̀ kò fẹ́ kí ìyapa ẹnu wà. Gẹ́gẹ́ bí Ìlànà oyè jíjẹ́ nílẹ̀ẹ̀bàdàn, bí Olóyè kán bá ti gbésẹ̀, kò sí àríyànjiyàn ẹni tó tọ́ tó yẹ ní Ìlànà oyè náà ní yóó gorí àpèrè.
Ní báyìí, akọ́dá awo tíí ṣe igbákejì Àràbà àná,ni àwọn tèwe tàgbà tí gbárùkù tì fún ìtẹ̀síwájú gbogbo onísẹ̀ṣe lápapọ̀.
Nígbà tí ìròyìn Òwúrọ̀ pé àgbà awo naa lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ ,o jẹ́ ó di mímọ̀ pé ní ìgbẹ́sẹ̀ oyè nílẹ̀ẹ̀bàdàn,ohun gbogbo pẹ̀lú ètò ni , bẹ́ẹ̀ ni kò dàrú rárá.
Ó ní Ìlọsíwájú bá onísẹ̀ṣe nípa pé wọ́n rí ìjọba ìpínlẹ bá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú akitiyan Àràbà àná yìí tí o sí di pé wọ́n bèèrè fún
ìsinmi enu ise ọba “Ìṣẹ̀ṣe day August 20, ọdọọdún.”À mọ̀ Gómìnà àná Abiọla Ajimobi kò fi ọwọ́ sí i,bi o tilẹ̀ jẹ́ pé Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ oyo fi ọwọ́ síi nígbà náà.
Ó ṣọ síwájú pé iṣu atẹnumọ́rọ̀ kìí jóná ní àwọn yóó fi ọ̀rọ̀ náà ṣe, òun sì gbà pé Olódùmarè yóó kàwọn yẹ,níwájú Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Onímọ̀ ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé torí pé òun ní àfojúsùn rere fún ìtẹ̀síwájú ìlú àti pé, àfojúsùn rere ní awo mímọ́ gbọdọ̀ ní,ojú òpó náà sì ni òun wà torí pé ọmọ àtàtà kìí borúkọ ẹbí jẹ́,ati pé èèyàn tó bá tí lórúkọ rere,kii wá àlàjẹ́ burúkú kún un.
Akọ́dá,Àgbàawo,Oloye Ifalere Ọdẹ́gbèmí Ọdẹ́gbolá11 ni Àràbà Ìbàdàn karùndínlọ́gbọ̀n (25). Òun tún fẹ́ẹ́ ẹ̀ ni Àràbà tó kéré jùlọ lọ́jọ́ orí tí ó fi dé ipò yí .
A bíi ní ọjọ́ kẹfà , oṣù kẹfà ọdún 1960. Ó bẹ̀rẹ̀ àkàsọ̀ oyè awo lọ́dún 1992, ó sì sún kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀ láti ọdún náà kí ó tó di Àràbà ní ọjọ́kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kọkànlá ọdún 2019.Èyí fihàn pé ìrìn àjò náà gbà á ní ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n kó tó goróyè.
Ìgbà yí ló sì di ọgbọ̀n ọdún àti oṣù mẹ́wàá tí bàbá a rẹ̀, Àgbà Oyè Ọdẹ́wùmì Àlàó Ọdẹ́gbolá1 fi ipò náà sílẹ̀ .
Bẹ́ẹ̀ Àràbà mẹ́ta lẹ́yìn ikú Ọdẹ́gbolá akọ́kọ́ ti jẹ ,kí ó tó padà kan Ọdẹ́gbọ́lá kejì.(11) .
Ìròyìn Òwúrọ̀ kí Àràbà awo náà pé àṣeyè ní àdáwọ́lé wọn gbogbo yóó jẹ́ ó.
iroyinowuro