Home / Àṣà Oòduà / Odun Iwude Ijesa: Gbogbo aye pejo saafin Owa Obokun

Odun Iwude Ijesa: Gbogbo aye pejo saafin Owa Obokun

Ese ko gbero lojo Satide to koja yii niluu Ilesa nibi ti tonile talejo ti gbe pejo lati sodun Iwude Ijesa laafin Owa Obokun Adimula ti ile Ijesa, Oba Gabriel Adekunle Aromolaran. Gege bi a se gbo, ayeye odun Iwude Ijesa yii lo maa n fun awon omo Ijesa lanfaani lati foju kan oba won laafin fun ikini odun eleyii ti ori ade naa yoo si ma sure fun gbogbo omilegbe ero ti won ba wa yo ayo odun naa.

Eyi nikan ko, oba naa yoo tun ni anfaani lati se abewo si awon ibudo isembaye kaakiri tibu-toro ilu ilesa gege bi asiwaju asa ati ise ilu naa. Bakan naa ni awon oba to wa ni gbogbo igberiko pata ni Owa Obokun yoo yoju si eleyii to je okan pataki lara ayeye Iwude Ijesa.

Ayeye to ti bere lati ojo Eti ni won fenu re kole lojo Abameta pelu orisiirisii ere idaraya bi ayo tita, ijo ati orin ibile, afihan awon ohun isembaye ati ojulowo aso ile Yoruba. Lara awon alejo pataki ti won pejo saafin Owa Obokun ni gomina ipinle Osun, ogbeni Aregbesola, ati oga olopaa ile Naijiria nigba kan ri, Ogbeni Mike Okiro.


Orisu

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...