A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-an
Bó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà bo
A dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀
Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o se
Ọ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú o
Baba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yè
Nítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nse
Ire oo
