Home / Àṣà Oòduà / “Oju Mimiko ni PDP yoo fi poora nipinle Ondo” – Oloye egbe APC

“Oju Mimiko ni PDP yoo fi poora nipinle Ondo” – Oloye egbe APC

Okan pataki ninu awon oloye egbe APC nipinle Ondo, Niran Sule-Akinsuyi, ti so yanya wi pe niseju Gomina Olusegun Mimiko ni egbe oselu PDP ipinle naa yoo fi di ohun a-fi-seyin teegun fiso.
Oro yii lo n so nigba to fi n da awon eniyan loju nipa aseyori ti yoo deba egbe APC ninu eto idibo gomina ipinle naa ti yoo waye lodun ti n bo.
 “Ki i se ero awon oloselu tabi egbe oselu APC nikan ni lati ni iyipada rere, awon ara ilu gan-an fe iyipada ti yoo so igbe aye won di otun. Eleyii si foju han ninu eto idibo aare to waye nibi ti egbe APC ti feyin PDP janle loju gbogbo aye,” Ogbeni Sule-Akinsuyi fi kun oro re bee.
Yato si eleyii, ojo Monde to koja yii ni awon omo egbe PDP meji kan tun kowe fi ipo won sile gege bi omo egbe, ti won si ko gbogbo awon ololufe won pata wonu egbe APC.
Awon oloselu meji naa ni ogbeni Ayo Patrick Akinyelure, eni to ti soju ekun aarin gbungbun Ondo gege bi senato nigba kan ri. Eni keji ni Pius Olakunle Osunyikanmi to je oludari Technical Aid Corps (TAC).
Awon oloselu nla mejeeji ti won jijo fi ipo won sile gege bi omo egbe PDP ni won salaye itesiwaju won sinu egbe APC gege bi iyipada otun fun Ipinle Ondo lapapo.
“Ka to to gbe igbese ti agbe yii, awon eniyan ti a n soju fun pata ni awon agbegbe wa ni won fowo si aba naa. Awon agbalagba egbe naa ko gbeyin, gbogbo won ni won fowo si igbese wa eleyii ti a lero wi pe yoo so eso rere,” Akinyelure fi kun oro re bee.

About oodua

One comment

  1. Hmmmn mimiko mimiko mimiko emelo ni mo pe e ?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

“Ijoba etan ati jaguda ni Mimiko n se nipinle Ondo” – APC

*Mimiko ya bilionu meedogun soto lati san gbese Lose to koja ni awuyewuye kan tun seyo nipinle Ondo nigba ti egbe oselu APC tako Gomina Olusegun Mimiko ti ipinle naa nipa bo se ya bilionu meedogun ati milionu mejo (N15. 8b) soto lati san gbese nikan. Owo ti Mimiko ya soto yii lo jeyo ninu eto isuna owo ipinle naa fodun 2016. Adari eto iroyin ati ipolongo fun egbe oselu APC, Ogbeni Steve Otaloro, lo tuto soke to si foju ...