Home / Àṣà Oòduà / O̩kùnrin àkó̩kó̩ lórí Te̩lifísò̩n l’Áfíríkà filè̩ bora

O̩kùnrin àkó̩kó̩ lórí Te̩lifísò̩n l’Áfíríkà filè̩ bora

Bí Kunle Ọlasọpe, ìlúmọ̀ọ́ká agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ṣe lo ìgbésí ayé rẹ̀ rèé o.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ wọ́n níjọ́ a kú,làá dère,èèyàn ò sunwọ̀n láàyè. ọrun dẹ̀dẹ̀ má kánjú gbogbo wa la ń bọ̀.
Olóògbé Kunle Ọlasọpe, tíí ṣe ọkunrin akọkọ to fi oju han lori i amóhùnmáwòrán ti waye, o si ti lọ, a mọ iṣẹ́ ẹ rẹ̀ ń tọ́ọ̀ lẹ́yìn.
Ọjọ Aiku, ọjọ Kẹfa, Osu Kẹwaa, ọdun 2019 ni gbajúgbajà agbóhùnsáfẹ́fẹ́ naa, Kunle Ọlasọpe sílẹ̀ bora lẹni ọgọrin ọdun.
Ó ní ifẹ si isẹ iroyin lo jẹ ko lọ si ileesẹ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ BBC lati lọ gba imọ kun imọ nipa isẹ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lọdun 1962.

Gẹ́gẹ́ bi itan igbe aye rẹ ti sọ fun wa lori ayelujara, baba to bi baba Olasope ni iyawo mẹwa, ti iya tirẹ si jẹ iyawo keji, ti oun naa si jẹ ọmọ kẹfa ninu ọmọ mẹrindinlọgbọn.

Ọmọ bibi ilu Ẹfọ̀n Alààyè ní ipinlẹ Ekiti ni Kunle Ọlasọpe, ti orukọ baba rẹ si n jẹ Julius Ọlasọpe.
Ilu Ibadan, ni ipinlẹ Ọyọ ni wọn bi Olasope si ni Ọjọ Kẹjọ, Osu Karun un, ọdun 1937 ladugbo Oke Padi
Ọlasọpe lọ si ile iwe alakọbẹrẹ Agbeni Methodist ni ilu Ibadan, ti o si wọle si ile iwe girama Igbobi, ni Yaba ni ilu Eko lọdun 1951


Bakan náà lo jẹ́ olori awọn akẹkọọ nile ẹkọ girama náà, kó tó kẹkọ ọ jade
fun eto ẹkọ fasiti, Ọlasọpe lọ si ibudo ẹkọ irọlẹ tíí se ẹka ileẹkọ fasiti Ile Ife tó kalẹ silu Ibadan


Nigba ti ẹrọ amóhùnmáwòrán de si Naijiria lọdun 1959, Kunle Olasope pẹlu Anike Agbaje-Williams ati John Edyang ni wọn bẹrẹ ikede ni ile isẹ móhùnmáwòrán WNTV, tíí se akọkọ nilẹ Afirika.
Gẹ́gẹ́ bi ẹni akọkọ to ka Iwe lroyin lori ẹrọ amóhùnmáwòrán , Ọlasọpe kopa nínú bi ile isẹ iroyin náà ṣe gbe afihan asa ilẹ wa, taa mọ si FESTAC 77 si ori afẹfẹ jakejado Naijiria.


Kunle Olasope gba ọpọ ami ẹyẹ.Diẹ lara rẹ ni ami ẹyẹ Naijiria (MON) lọdun 2000, t’íjọba ipinlẹ Ekiti náà si fi ami ẹyẹ daa lọla lọdun 2004
Olasọpe, nigba aye rẹ ma n parọwa si àwọn ọdọ láti jara mọ iṣẹ́ ti wọ n n se, ki wọn si yago fun wiwa owo ojiji.


Nigba to jẹ pe ile ni abọ sinmi oko, Kunle Ọlasọpe kó lọ silu Ẹfọn Alààyè lẹyin tó fẹyinti lẹ́nu isẹ, to si ń kopa lọkan o jọkan si idagbasoke ilu náà
Ọlasọpe ni iyawo, to si bi ọpọ ọmọ ki iku to paju ẹ de lẹni ọdun mejilelọgọrin loke eèpè.
Ǹ jẹ́ kí Èdùmàrè ó dẹlẹ̀ féèyàn rere.

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo