Ojo ibi baba tun ti wole de. Ki n maa paro, owo mi n gbon, mi o si mo ohun ti maa ko gan-an lati fi ki baba rere. Mi o tile mo iru agbekale asanyan oro ti mi o ba lo to le se aponle baba bi mo se fe gan-an lokan mi. Baba je eni to nifee, ti won si ko opolopo eniyan mora. Bi ohunkohun ba ru ni loju, ti e ba pe baba, suuru ati ayo ni baba fi n dahun.
Adura mi ni wi pe ke e pe laye, ninu alaafia, ifokanbale, ogbon ati ilera to peye. Tope Falaanu ni ki n ki yin, Adewale Dada Thegood naa si fise ran mi. Won ni igba odun, odun kan ni. Ase
Olatunbosun Oladapo ti bere si ni se afihan awon aworan won aye atijo lati fi dupe lowo Oluwa fun irin-ajo odun mejilelaadorin ti won ti n ba bo lori erupe ile. Awon aworan naa ni yii nisale pelu awon akole baba:
Orisun: olayemioniroyin