Gégé bí odún egúngún odoodún se ma bèrè l’óla, ojó ajé, ní ìlú Ibadan, ní ìpínlè Oyo, Olúbàdàn ti ilè Ibadan, oba Saliu Akanmu Adetunji ti pè fún àláfíà láti òdò àwon eléégún àti àwon tí ó ń tèle tí kò ní lò ju òsè méta lo.
Oba Adetunji ti ń se odún egúngún l’ódoodún láti tèle Àsà àti ìsèse ilè Ibadan, kìlò pé kí wón má so odún náà di bí o lo yàgò fún mi fún àwon èèyàn.
Oba, nínú ìfòrò wá ni lénu wò rè tí Olùdarí Media and public affairs, Adeola Oloko bu owó lù, tí ó te àwon oníròyìn l’ówó ní ìròlé ojó Àìkú sopé àwon Agbófinró ti fi àwon ènìyàn l’ókàn balè wípé àwon setán láti fi ìdí òfin múlè nípa gbígbé àti pí pè l’éjó enikéni tí ó bá gbèrò láti da odún náà rú.
Gégé bí oba, èbè mi sí àwon ènìyàn wa ni láti se odún náà ní ònà tí ó tèlé òfin.
“Bákan náà, màá ro àwon ènìyàn wa láti yàgò fún lílo àwon ohun ìjà olóró bí ìbon, àdá àti ìgò àkúfó kìí se tí won bá ń se odún lówó nìkan sùgbón léyìn odún náà, tí ó jé wípé owó òfin kò ní fi enikéni tí ó bá se jàgídíjàgan sílè “ó so béè .
Omo oòduà rere se ìrántí pé odún tí ó lo nìkan, okò tí ó tó méjìdínlógún ni won bàjé ní ònà Akuro àti ònà Igbonna, Ibadan nígbà tí egúngún àti àwon tí ó tèle bá ara won jà.
Agbó wípé ojó kerin osù kefà (June 4) ló ye kí Odin náà kókó bèrè sùgbón wón sún-un-sún-un sí ojó kejì osù keje (July 2) látàrí ìdábòbò tí kò tètè sí….
Continue after the page break for English translation