Omokúnrin kékeré kan ní won ti mó’ lé ní àgó olópàá látàrí ìbèrù tí ó ní fún àwon olópàá.
Gégé bí ìròyìn se so, omokùnrin odún métàlá, tí ó sí jé olórí okúnrin ilé-èkó won, ni ó n pon omi lówó nínú kànga ní iwájú ilé won, nígbà tí ó rí àwon oní jàgídíjàgan ní Itafaji, ní ìpínlè Eko .
Bàkan náà, látàrí ìbèrù tí ó ní fún àwon olópàá ló mu féré ge nígbà tí ó rí won, èyí sìni èsè rè tí won fi mu láti tì mólé.
Gégé bí won se so, won ní ó wà lára àwon oní jàgídí jàgan tí ó sá lo, gbogbo wàhálà àwon ará àdúgbò ló sì jásí asán láti jékí won fi sílè, báyìí ni won se mú omo yí àti ìyá rè lo.

Àṣà Oòduà Àṣà Oòduà

One comment
Pingback: Omokùnrin odún métàlá (13) ni àwon olópàá ti mú látàrí ìbèrú tí ó ní sí won. – Naija Curator