Home / Àṣà Oòduà / Òrìsà tí ń darí aféfé

Òrìsà tí ń darí aféfé

Oya òpèré,
Ekùn oko asè’ké
Oya má bá mi jà
Mi ò l’ówó aféfé ńlé

Èmi ò rí eni tí yó ràgàn, ràgàn bí Oya ní òde ìpo
Kò séni tí ó ràgàn ràgàn bí Oya lótù ifé

Oya lo ràgàn ràgàn
Ló re nú ìgbé lò ké sí
Omo oyá d’olú
Oya mòdè ooo

Òpèré ní won ń jé
Òpéré ni won jé ó e
Gbogbo ilé olóya
Òpérè ni won je o e

Oya ní ìyá òun ò l’órogún
Óní òun náà ko ní l’óba kan
Òrìsà mérìndínlógún ni Oya bá n’ílé Sàngo gbogbo won ló fi eyin ojú lé lo. .

About Awo

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...