Home / Àṣà Oòduà / “Oruko awon to ja Naijiria lole ko ni pe jade” – Buhari

“Oruko awon to ja Naijiria lole ko ni pe jade” – Buhari

Aare Buhari ti fi da awon omo Naijiria loju wi pe, laipe, awon oruko awon ojelu ti won ko owo Naijiria je ko ni pe di tite jade fun gbogbo aye. Gege bi oro re, eleyii to se nibi ipade Anyiam-Osigwe Foundation to waye nilu Abuje lose to koja, ibe ni aare ti n so wi pe awon oruko yii ni banki agba ile yii, Central Bank of Nigeria (CBN) ti se akojopo won.

Sugbon won da atejade naa duro latari awon iwadii kan ti n lo lowo labenu. Aare tun fi kun un wi pe pupo ninu awon eniyan yii ni won ti n da lara awon owo naa pada si asunwon ijoba nipase eto igbogun ti iwa jegudujera ti n lo lowo.

“A ti gbe awon igbese to joju lati ri awon owo ti won je mole yii gba pada. Mo si fi da yin loju wi pe iwadii to fese mule n lo kaakiri tibu-toro ile yii ni awon eka ile ise ijoba pata. Awon osise tabi awon ti won wa nipo agbara ni awon igba kan seyin naa pelu awon ti a n tanna wadii wo. Awon ti won ba fe aponle, anfaani wa lati da awon owo naa pada lai si wahala.

“Mo si fi n dayin loju wi pe oruko awon asebaje yii pata ni banki agba yoo gbe jade. Ohun to fa ti a fi dawo atejade naa duro ni wi pe, igbejade awon oruko naa ni akoko yii le se akoba fun awon iwadii kan ti n lo lowo. Sugbon gege bi ara ilu to ran wa nise, a fi dayin loju wi pe dandan ni ka jabo fun yin nigba ti akoko ba to,” Buhari se lalaye bee.

 

Olayemioniroyin

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Buhari kí Obaseki kú oríire

Buhari kí Obaseki kú oríire Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ránṣẹ́ kú orííre sí Godwin Obaseki lẹ́yìn tó jáwé olúborí nínú ìdìbò gómìnà tó wáye lónìí nípìnlẹ̀ Edo. Obaseki tó jẹ́ olùdíje dupò gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló fi ìdí akẹgbẹ́ rẹ̀ lábẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC Ize-Iyamu janlẹ̀. Nínú àtẹjáde náà ti Garba Shehu tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Ààrẹ Buhari lórí ìpolongo fọwọ́sí, ló ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn elétò ìdìbò fún bi wọ́n ṣe kéde Obaseki bí ẹni to ...