Seyi Makinde ṣe àbẹ̀wò sí ibùdó ìtọ́jú èèyàn 200 tí ọlọ́pàá tú sílẹ̀ ní ilé Ọlọ́rẹ
Fẹ́mi Akínṣọlá
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
Seyi Makinde ti se àbẹ̀wò sí ilé Ọlọrẹ tó wà ní àdúgbò Ọ̀jọ́ nílùú Ibadan .
Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, ilé yìí ni ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ èèyàn mẹ́rin tí wọ́n kó àwọn èèyàn ní ìgbèkùn lọ́jọ́ Ajé.
Èèyàn okòólénígba àti marùn ún ni wọn tú sílẹ̀ nínú ilé náà, tí wọ́n tún ń lò bíi mọ́sálásí.
Lásìkò tó se àbẹ̀wò síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni Gómìnà Makinde ti pàṣẹ pé kí wọ́n wó Mọsalasi ọ̀hún pátápáta.
Bákan náà ló tún ṣe àbẹ̀wò sí ibùdo tí wọ́n tí ń se ìtọ́jú àwọn èèyàn ti wọn tu silẹ ninu igbekun ni mọsalasi ọhun.