Akeredolu yari kanle. Olubadan ni ki Seriki Sasa fi owo sibi owo o gbe…
. Akeredolu yari kanle
. Olubadan ni ki Seriki Sasa fi owo sibi owo o gbe
. Gani Adams n yona lenu lori laasigbo Wakili
. Sunday Igboho si gegun kale
Igbaniloju naa ti n lo, ojo pe die, sugbon bayii, o jo pe ile Yoruba ti setan ati gba ara re kale lowo ajeji godogba to n te’le basubasu.
Awon atilaawi yii gan-an ni awon Fulani, paapaa awon darandaran, awon ti won je oniwakiwa ninu won.
Awon lo n ko ogun ja omo Alade.
Awon ni won n da maaluu je oko, ti won n sa oloko ladaa, ti won n yin omo onile nibon, ti won n fipa ba omo ati iyawo won lopo, ti won si n jiwon gbe, ti won n pa eniyan bo se wu won.
Nnkan naa buru debi pe won n fi owo ola gba tomode tágba loju.
Yala ni Ipinle Oyo ni o, Ogun ni o, Ondo ni o, Ekiti ni o tabi Osun, awon karanbaani naa ko bikita.
O ti n sele, o ti pe, sugbon ti enu odun bii merin seyin yii lo gontio.
Idi niyi ti awon eniyan kan fi ro pe tori pe Fulani ni olori Naijiria bayii ni awon darandaran se n se bo se wu won.
Yoruba bo, won ni a kii ba nii tan, ka fa ni nitan ya.
Won ni a kii gbe ile eni ka forun ro, sugbon bii ti eni alakatakiti Fulani ba lalejo ko.
Awon ti won buru jae debi pe won n ji olowo gbe, won n pa oba alaye, won si n daamu gbajugbaja bii Ojogbon Wole Soyinka.
Nje efuufu lele to n da ologi laamu, ko ti so ti elelubo dófo?
Sugbon lenu ojo meta yii, o jo pe ile Yoruba naa ti n so pe o to gee.
Won reti, reti ki ijoba apapo ati awon agbofinro o dekun galegale darandaran ati awon eniyan to n gba won sabe, sugbon ko jo pe won se bee.
Dipo bee, ohun ti awon kan n ko lorin ni pe ko dara ki a maa so awon eya kan loruko, ati pe ko si eya ti odaran ko si.
Eki akoko ti Olorun koko ran si omo Alade ni Sunday Igboho.
Asiko to siwaju ogun Igangan lo jo pe afefe to fe si awon olori ati eleyin Yooba niye.
Oun lo je ki awon ara oke ohun naa mo pe omi le dake roro, kii se pe ko le gbeni lo.
Eni kan ti Olorun tun fi se sababi ni Gomina Ipinle Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu.
Oun lo fi Ondo han omo Naijiria, nipa bi o se dide ogun si awon odaran darandaran ti won fi inu igbo ipinle naa se ibujokoo.
Bi o tile je pe omo egbe APC to je ti ijoba apapo ni Akeredolu, bi eni pe Akereyari lo se se.
Ko woju Are Muhammadu Buhari rara.
O ni dandan, awon ajeji odaran gbodo fi Ondo sile, ki won jade ninu igbo ijoba, iyen Reserved Forests.
Ko pin sibe o, Akeredolu ti fe so di ofin pe eni kankan ko gbodo maa san naani ori, ki won maa daran kaakiri ipinle naam o, iyen open grazing.
Koda, o ti gbe abadofin naa lo si ile igbimo asofin.
Ko wa tan bi, ma rin laala mi, ojo kan laa ko o.
Ohun ti igbese Akeredolu fi ya opo eniyan lenu ni pe won gba pe awon Buhari lo gbe e wole gomina, paapaa ni igba to koko wole alakoko.
Arakunrin naa wa fihan pe aabo ilu se pataki si oun ju ohunohun lo.
Pelu igbese ti Akeredolu wag be yii, lori ofin ma da maalu lori ile mi mo, o jo pe o ti le awon gomina egbe re ni ile Yooba si are, o ti fa won sirin, ti awon eniyan tiwon naa yoo maa wo o bi won yoo se ofin naa, tabi won ko nii se e.
Olubadan ti ile Ibadan, Oba Saliu Adetunji, naa fakoyo lose to koja, lori oro galegale awon ajoji godogba yii naa ni.
Opo eniyan lo ti n kominu lori bi awon Seriki Fulani se n se bi oba alaye, ti si n se bi eni ju oba lo nibo miran.
Apere eyi ni Sarkin Sasa, Alhaji Haruna Mai Yasin Katsina.
Enu ti n kun Seriki yii. Ile ta si i.
Igba ti ija nla be sile ni Sasa laipe yii ni oro naa wa le kenka.
Bi oba alaye ni o n se, eyi ti awon onwoye kan so pe ejo ti fe lowo ninu.
Won ni se oba meji lo wa nÍbadan ni?
Sugbon lose to lo, Olubadan pa a lase pe, o to gee, alubata kii darin.
Won ni oba kii pe meji laafin, ijoye le pe mewaa.
Olubadan pa a lase pe Seriki Sasa gbodo fi ara re si abe Baale Sasa, Alagba Amusa Ajani.
O ni ninu ofin ile Ibadan, Baale ni olori agbegbe kookan.
Lobatan, se ika kan ni olohun fii mu nnkan re!
Eni kan to tun ti n ja fitafita lenu ojo meta yii ni Aare Ona Kakanfo ile Yoruba, Iba Gani Adams.
Egbe Oodua Peoples Congress, eyi to je olori fun, lo tun gbe igbese nla kan, ti won lo digbo lu arakunrin Fulani kan ti won ni ebo wa leru re, iyen, Wakili.
Esun ti won fi kan Wakili ni pe oun lo wa nidii opo iwa aidaa to n sele ni agbegbe Ibarapa.
Bo tile je pe oro naa ti di isu ata yan-an-yan-an, nipa pe awon olopaa ti gbe awon omo OPC to lo mu Wakili mole, oye oun to n sele ti ye awon eniyan si i.
Idi niyi ti Iba Gani Adams fi wa n ja fitafita, to ni egbin to n gun omo Yooba gbodo wa si opin.
Ohun idunnu wa lo je lose to lo bakan naa, nigba ti Arae Muhammadu Buhari pa a lase pe enikeni to ba ti gbe ibon AK-47 lowo, lai lase lati se bee, ki awon agbofinro maa mu won bale ni.
Eyi mu ki inu opo eniyan dun pe kii se pe Aare dunnu si bi awon darandaran ati awon odaran mira se n gbe irufe ibon naa kaakiri.