Orí kó mi yọ lọ́wọ́ àwọn agbébọn – Gómìnà Samuel Ortom
Fẹ́mi Akínṣọlá
Gómìnà ìpínlẹ̀ Benue Samuel OPrtom ti fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ làwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí òun lógúnjọ́ oṣù Kẹta.
Gómìnà náà sọ pé àwọn agbébọn tí wọ́n dojú ìjà kọ àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ wọ aṣọ dúdú tí wọ́n sì tó mẹ́ẹ̀ẹ́dógún
ó ní àwọn agbébọn yìí fẹ́ rán òun lọ sí ọ̀run àrèmabọ̀ ni nítorí ó tó kìlómítà méjì tí àwọn fi sá fún wọn.
Lásìkò tó n bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ni Ortom tú kẹ̀ẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ ,ó ṣàpèjúwe àwọn agbébọn yìí gẹ́gẹ́ bíi darandaran tó sì ní bíi àwọn mẹ́ẹ̀édógún ni wọ́n tọ ipasẹ̀ òun dé etí odò t’óun ti n fẹsẹ̀ rìn.
Gómìnà Ortom jẹ́ èèyàn kan tó n bẹnu àtlẹ́ lu ìhùwàsí àwọn darandaran tó jẹ́ ìpèníjà ààbò ní Nàìjíríà lẹ́nu lọ́họ́ọ́lọ́ yìí.