Home / Àṣà Oòduà / Ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ kò sọ pàtó ẹni tó jáwé olúborí láàrín Makinde àtiAdelabu

Ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ kò sọ pàtó ẹni tó jáwé olúborí láàrín Makinde àtiAdelabu

Ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ kò sọ pàtó ẹni tó jáwé olúborí láàrín Makinde àtiAdelabu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kángun kàngùn Kángun, bọ́ pẹ́,bọ́ yá, ó gbọ́dọ̀ kángun síbìkan, bẹ́ẹ̀ ló súmọ́ kí ọ̀rọ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, látàrí àgbéjáde ilé ẹjọ́.
Tí Ilé ẹjọ́ kan kò bá wá fìdíi ọ̀rọ̀ múlẹ̀ ní pàtó nípa ìdájọ́ ohun ta gbé lọ síwájú rẹ̀, kínni ó yẹ ká ṣe?
Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nílùú Ibadan tó ń gbẹ́jọ́ láàrin Gómìnà Seyi Makinde àti akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ du ipò Gómìnà, Adebayo Adelabu ti ẹgbẹ́ òsèlú APC.

Kókó ọ̀rọ̀ tó jáde nípa ìdájọ́ tí adájọ́ ẹlẹ́ni mẹ́ta ilé ẹjọ́ náà fi lélẹ̀ ni pé àwọn fọwọ́ rọ́ ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbẹ́jọ́ ìdìbò sẹgbẹ kan ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ kò sọ ojú abẹ níkòó bóyá Makinde tàbí Adelabu ló jáwé olúborí.

Ní ti Adelabu, ń se ló ń sọ pé kí Ilé ẹjọ́ wọ́gilé èsì ìdìbò tó gbé Makinde wọle kó sì kéde òun gẹ́gẹ́ bí Gómìnà.
Àmọ́ báyìí tí Ilé ẹjọ́ náà kò ì sọ bóyá òun ni Gómìnà tàbí Makinde ni, ohun tó kàn fáwọn méjéèjì ni kí wọ́n gba Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ láti yànànà ọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

Lójú òpó Twitter, ohun tí Ilé ẹjọ́ yí sọ tí ń mú ìríwísí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá táwọn èèyàn sì ń gbìyànjú láti tú ohun tí Ilé ẹjọ́ sọ bó ṣe yé wọn mọ.
Kódà àwọn kan ti ń fi ohùn ránṣẹ́ sí Ààrẹ Buhari àti ẹgbẹ́ APC pé kí wọ́n má ṣe dásí ọ̀rọ̀ náà tí wọn ò bá fẹ́ kan àbùkù

Bí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe wà báyìí,ohun tó dájú ni pé ilé ẹjọ́ kò sọ ẹni tó jáwé olúborí bẹ́ẹ̀ sì ni kó kéde pé wọn yóó tún ìbò mìíràn dì
Bí a bá ní ká tẹ̀lé ọ̀rọ̀ táwọn agbẹjọ́rò olùdíje méjéèjì yí sọ báyìí, ààyè ṣì wà nílẹ̀ fáwọn láti kọrí sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ láti sọ bí iṣu ṣe kú, bọ́bẹ ṣì ṣe pá.
Kókó kan ṣoṣo tó hànde lórí ọ̀rọ̀ ẹjọ́ yìí ni pé Ilé ẹjọ́ gíga ló máa yanjúẹ̀.

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo