Home / Àṣà Oòduà / Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ máa wo̩lé láìpé̩

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ máa wo̩lé láìpé̩

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ máa wo̩lé láìpé̩

Gbogbo igbiyanju ni awon ajo eto eko ti wa ninu awon ajo NCDC n se bayii lati le je ki awon akekoo wole eko won.


Oro arun coronavirus yii ti su gbogbo aye. Ile ti su awon akekoo, awon ile-iwe aladaani n gbiyanju eto eko ori ayelujara, bi o tile je pe “oju apa ko jo oju ara”. Eto eko oju ofurufu ko rorun bii ti ojukoju.


Bi awon akekoo se n saroye pe eto eko naa ko da bii ki awon ri akegbe awon ni awon oluko naa ni “ki owo ma dile lasan ni”.


Awon oluko kan tile ni awon ise kan ko tile see fi ogbon ko rara loju ofurufu, awon ise bii aworan yiya, ina dida, abala isiro Kan ati gbogbo ise to nilo ki awon akekoo dan wo loju oluko.


Awon obi gan-an n saroye nipa ohun ti eto eko ayelujara naa n gbe lo lapo won nipa data rira, epo petiro ati awon nnkan miiran. Awon obi ni bee ni ko si owo lowo.


Eyi to tun wa dun awon oloju aanu ju ni awon akekoo ile iwe ijoba ti ko si anfaani foonu tabi komputa fun rara.


Eyi naa mumu laye ijoba apapo nitori opo awon oluko ile-iwe aladaani ni won je, ko sise, ko sowo fun. Ipade osan ati oru ti n lo lati wo bi awon Kan se maa lo ile-iwe ni aaro ti awon Kan maa lo losan lati le din ero ku die.

Ìròyìn láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí

About ayangalu

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.