Home / Àṣà Oòduà / Àwọn nọ́ọ̀sì fẹ̀hónú hàn l’America nítorí àìsí èròjà láti gbógun ti Covid-19

Àwọn nọ́ọ̀sì fẹ̀hónú hàn l’America nítorí àìsí èròjà láti gbógun ti Covid-19

Ẹgbẹ́ àwọn nọ́ọ̀sì kan, National Nurses United ti fẹ̀hónúhàn ní gbàgede Ilé Ìjọba America, White House, láti késí àwọn Gómìnà àti Ìjọba àpapọ̀ pé kí wọ́n ó pèsè èròjà ìdáàbòbò ara ẹni fún àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera tó ń gbógun ti àrùn apinni léèmí coronaviurs.

Àwọn nọ́ọ̀sì náà sọ pe “ti ẹ ko ba daabo bo wa, a ko le daabo bo awọn alaisan wa’’.

Oríṣìríṣi àwòrán àwọn nọ́ọ̀sì àti dókítà tí Covid-19 ṣekúpa, àti àkọlé ni àwọn nọ́ọ̀sì náà gbé dání.

Ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́jọ nọ́ọ̀sì ló wà nínú ẹgbẹ́ náà, òun sì ni ẹgbẹ́ àwọn nọ́ọ̀sì tó tóbi jù l’Amẹ́ríkà

About ayangalu

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.