Home / Àṣà Oòduà / “Ayojuran ni Mimiko lo se niluu Bayelsa”- Egbe APC

“Ayojuran ni Mimiko lo se niluu Bayelsa”- Egbe APC

Awon omo egbe oselu APC eka ti ipinle Ondo ti bu enu-ate lu Gomina Olusegun Mimiko ti awon kan tun pe ni Iroko gege bi asaaju ti ko mo eyi to kan lati muse. Atejade yii lo jade nigba ti won gburo gomina naa nipinle Bayelsa nibi to ti n lewaju ipolongo ibo fun gomina Henry Seriake Dickson tipinle naa to je omo egbe PDP.

Gege bi adari ipolongo ati iroyin fun egbe APC ti ipinle Ondo, Ogbeni Steve Otaloro, so wi pe, ijoloju lo je wi pe gomina le raaye ma ru eru eleru lori nigba to n wo eru ti e nile geerege.

“Pelu gbogbo laasigbo ti ipinle Ondo wa, to je wi pe ilaji ipinle naa lo wa ninu okunkun birimubirimu, ti eto oro aje si ti di akurete patapata, o je kayeefi wi pe gomina tun le roju-raaye gbe eru eleru lori nigba ti tie si n wole geerege bi igba ti omin wo yanrin. Awon igba ati akoko ti gomina n lo loke okun lati gbajumo awon oro ara re nikan ati idile re ju eyi to n lo lati mu igba derun fun awon ara ilu ti won gbe depo agbara lo.”

Ogbeni Otaloro tun salaye siwaju, ” Bi mo se n ba yin soro yii, iye ti awon ileepo n ta epo pentiro ju iye owo ti ijoba apapo ni ki won maa ta a lo ni ipinle Ondo. Gbogbo eleyii si ni asiri re ti tu si wa lowo. Mimiko lo se ipade pelu awon alagbata epo lati se eleyii ni ona  a ti tabuku ijoba apapo nipinle Ondo,” Ogbeni Otaloro fi kun oro re bee.
http://www.olayemioniroyin.com/

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

“Ijoba etan ati jaguda ni Mimiko n se nipinle Ondo” – APC

*Mimiko ya bilionu meedogun soto lati san gbese Lose to koja ni awuyewuye kan tun seyo nipinle Ondo nigba ti egbe oselu APC tako Gomina Olusegun Mimiko ti ipinle naa nipa bo se ya bilionu meedogun ati milionu mejo (N15. 8b) soto lati san gbese nikan. Owo ti Mimiko ya soto yii lo jeyo ninu eto isuna owo ipinle naa fodun 2016. Adari eto iroyin ati ipolongo fun egbe oselu APC, Ogbeni Steve Otaloro, lo tuto soke to si foju ...