Home / Àṣà Oòduà / Èeyàn 239 míràn ni àrùn Covid-19 lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Èeyàn 239 míràn ni àrùn Covid-19 lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Èeyàn 239 míràn ni àrùn Covid-19 lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà

À fi kí Ọlọ́run sàánú wa lórí àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì yìí tó ń gbomi lójú t’olórí t’ẹlẹ́mù, bí Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí tún kéde àwọn ènìyàn tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì.
Ní báyìí, ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin lé ni ọ̀kànléláàdọ́jọ (4151) ló ti ní àrùn náà ní Nàìjíría.

Àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn lọ́rílẹ̀-èdè Nàìjíríà (NCDC) kéde lórí àtẹjísẹ́ wọ́n lálẹ́ ọjọ́ sátide ló fi ìkéde náà síta.

Gẹ̀gẹ́ bí àjọ náà ṣe sọ, ẹ̀nìyàn mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún (97) ló lùgbàdì arùn náà ni ìpínlẹ̀ Èkó, mẹ́rìnlélógójì (44) ni Bauchi, mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ní Kano àti mọ́kàndílógún (19) ní Katsina.

Ìpínlẹ̀ Borno ní mẹ́tàdínlógun (17), Abuja ,ènìyàn méje (7), Kwara mẹ́fà (6), Ọ̀yọ́ márùn-ún (5) nígbà tí Sokoto àti Adamawa ní ènìyàn mẹ́ta-mẹ́ta.

Kebbi, Ogun àti Plateau ní ènìyàn méjì-méjì nígbà tí Èkìtì ní ènìyàn kan soso.

Láti ìgbà ti àrùn náà ti bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàdílọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2020, ni ó tí tàn kálẹ̀ sí ìpínlẹ̀ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n àti Abuja báyìí.

Ìpínlẹ̀ Èkó náà sì ni ìpínlẹ̀ tó ní ènìyàn tó pọ̀ jù nítórí ibẹ̀ ni a ti rí ẹni àkọ́kọ́, ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀run kan ààbọ ló ti ní àrùn náà ní ìpínlẹ̀ Èkó, Ìpínlẹ̀ Kano ló tèlé, pẹ̀lú ènìyàn ọgọ́rùn márùn lé mẹ́rìndinlọ́gọ́rin, lẹ́yìn náà ni Àbújá tí òǹkà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ènìyàn ọ̀ọ́dúnrún lé mẹ́tàlélógójì ló ti lùgbàdi àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ ọ̀hún.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.