Home / Àṣà Oòduà / “Idagbasoke awon akonimoogba gbodo je koko fun NFF” – Amodu

“Idagbasoke awon akonimoogba gbodo je koko fun NFF” – Amodu

Shuaibu Amodu, okan lara awon igbimo oludari ajo NFF ti so wi pe ona kan pataki lati se igbelaruge fun ere boolu alafesegba abele ni nipa sise eto idagbasoke fun awon akonimoogba ere boolu ile Naijiria. Oro yii ni Amodu, eni odun metadinlogota (57) se niluu Minna nigba ti won pate idanileko ita gban-angba fun awon akonimoogba ere boolu ile Naijiria.

“A le yanju isoro ti n koju ikoni awon ojewewe agbaboolu ile wa ti won gba boolu labele nipa sise agbekale awon eto to giriki fun idagbasoke awon akonimoogba wa gbogbo,” Amodu fikun alaye re bee.

Amodu, eni to ti fi igba kan je akonimoogba egbe agbaboolu Orlando Pirates ti ilu South Africa tun so wi pe, aseyori Golden Eaglets ninu idije 2015 FIFA U-17 World Cup ko fi bee wu oun lori nitori wi pe pupo awon omo naa ni ko gba abe itoju boolu abele ile wa koja. O si tun so wi pe ona kan pataki lati da ogo boolu ile Naijiria pada ni pipada si ese aaro fun atunse to munadoko.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Manchester United Ti Se Tán Láti Ra Odion Ighalo Pátápátá

Manchester united ti se tán láti ra Odion Ighalo pátápátá Lati owo Akinwale Taophic Se won ni ti egungun eni ba jo re, ori a ma ya atokun re. Ati wi pe, Ku ise ni n mu ori eni ya! Gudugudu meje ati yaaya mefa ti atamatase fun orileede wa Nigeria ni igba kan ri, eni ti o darapo mo iko Manchester United ninu osu kini odun ti a wa yi pelu adehun alayalo lati inu iko egbe agbaboolu Shanghai ...