Home / Àṣà Oòduà / “Ijoba etan ati jaguda ni Mimiko n se nipinle Ondo” – APC

“Ijoba etan ati jaguda ni Mimiko n se nipinle Ondo” – APC

*Mimiko ya bilionu meedogun soto lati san gbese

Lose to koja ni awuyewuye kan tun seyo nipinle Ondo nigba ti egbe oselu APC tako Gomina Olusegun Mimiko ti ipinle naa nipa bo se ya bilionu meedogun ati milionu mejo (N15. 8b) soto lati san gbese nikan. Owo ti Mimiko ya soto yii lo jeyo ninu eto isuna owo ipinle naa fodun 2016.

Adari eto iroyin ati ipolongo fun egbe oselu APC, Ogbeni Steve Otaloro, lo tuto soke to si foju gbaa ninu atejade kan to fi sowo si awon oniroyin niluu Akure.

Ninu atejade naa lo ti bu enu ate lu ijoba Mimiko gege bi ijoba etan ati jaguda paali ti n fi owo mejeeji ko owo ilu mi bi kalokalo.

“Bawo ni ijoba yoo se ya N15.850b soto lati san gbese nikan, eleyii ti n se ida ogbon ninu ogorun (30%) owo isuna odun kan soso. Kosi tabisugbon ninu oro to wa nile yii, egbe PDP ti ta ojo ola ipinle Ondo danu,” Ogbeni Otaloro se alaye re bee.

Bakan naa ni Ogbeni Otaloro tun tenu mo wi pe, awon ise akanse ti Mimiko salaye ninu iwe eto isuna wi pe awon fe na aadota bilion ati milionu mesa-an (N50.9 b) le lori, lo je awon ise ti won ti yo owo re soto tele ni awon igba kan seyin.

Ogbeni Otaloro ko sai tun gbe orinkiniwin alaye re kale nipa bi ijoba PDP ti Mimiko ko sodi se ja awon eniyan ipinle Ondo ni jibiti tirilionu kan naira eleyii to je owo ti ipinle naa pa wole lati odun bi 2009.

Wayio, Ogbeni Otaloro ti gba Mimiko niyanju lati wo awokose Muhammadu Buhari, eleyii to je wi pe larija eto isuna owo re da lori ona lati mu aye derun fun awon mekunnu.

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

“Ayojuran ni Mimiko lo se niluu Bayelsa”- Egbe APC

Awon omo egbe oselu APC eka ti ipinle Ondo ti bu enu-ate lu Gomina Olusegun Mimiko ti awon kan tun pe ni Iroko gege bi asaaju ti ko mo eyi to kan lati muse. Atejade yii lo jade nigba ti won gburo gomina naa nipinle Bayelsa nibi to ti n lewaju ipolongo ibo fun gomina Henry Seriake Dickson tipinle naa to je omo egbe PDP. Gege bi adari ipolongo ati iroyin fun egbe APC ti ipinle Ondo, Ogbeni Steve Otaloro, ...