Home / Àṣà Oòduà / Nipinle Ondo, awon osise ko rowo osu gba lati sodun Keresimeis

Nipinle Ondo, awon osise ko rowo osu gba lati sodun Keresimeis

*Ijoba da awon osise 62 duro lenu ise
Orisun: Olayemioniroyin.com
Nibayii, Trade Union Congress (TUC) eka ti ipinle Ondo ti n ro gomina ipinle naa, Olusegun Mimiko, lati san awon owo osise ti won je seyin ati awon ajemonu won saaju ki odun keresimesi ti n bo yii to wole de.

Egbe ti n ja fun eto awon osise yii tun fi kun wi pe, o je edun okan nla fun egbe naa bi ijoba ipinle Ondo se da awon osise mejilelogota (62) duro lenu ise.

Oro yii lo jade ninu atejade ti egbe naa fi sita eleyii ti alaga egbe naa, Comrade Ekundayo Soladoye ati akowe re, Fatuase Clement buwolu.

Gege bi alaye to te Olayemi Oniroyin lo, won ni ohun to le mu awon osise yo ayo idunnu odun keresimesi to n bo yii ni ti won ba ni owo lapo lati se itoju ebi won. Won si n fi asiko naa rawo ebe si Gomina Mimiko lati siju aanu wo awon osise ipinle naa. Ogbeni Kayode Akinmade, komisanna fun eto iroyin, ni ki awon osise lo mokan bale wi pe owo won ko ni pe jade.

Ninu alaye Komisanna, o ni eto oro aje to denu kole lo fa sababi ti ijoba ipinle naa ko fi ri awon owo osu naa san. O si se ileri wi pe laipe, awon owo naa yoo di sisan.

Ogbeni Akinmade tun soro lori awon osise ti won da duro lenu ise. O ni ijoba ko da enikeni duro lona aito tabi lai tele ofin.

“Ti a ba ri eni ti ijoba daduro lona aito, e pe ki won mu awon eri won wa siwaju. Gbogbo awon ti ijoba da duro lo nidi kan pataki, eleyii ti ijoba si se ohun to to labe ofin,” Komisanna fi kun oro re bee.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

È̩yin òsìsé̩ mi nílò àyè̩wò coronavirus kíákíá- Akeredolu

È̩yin òsìsé̩ mi nílò àyè̩wò coronavirus kíákíá – Akeredolu Arakunrin Rotimi Akeredolu ti o je gomina ipinle Ondo lo n gba awon alabasise re niyanju ki won fi oro ti oun se arikogbon. O ni iba lasan ni o se oun ti oun si se itoju ara laarin ojo meji pere. O ni leyin re ni awon ore gba oun nimoran lati se ayewo ajakale arun coronavirus. Gomina naa ni “iyan jija lo n ba ore je” oun se ayewo ...