Home / Àṣà Oòduà / Ojúmọ́ Kan, Oògùn Kan

Ojúmọ́ Kan, Oògùn Kan

Ilu nla bii orileede Naijiria sowon lagbaye. Ko si odun kan tabi osu kan to le lo lofee ki o ma se si ohun kan ti a maa gbe poori enu.


Igba miiran, o le je Obasanjo lo maa ko leta si Aare to maa dogun dode.
Lenu odun yii nikan ni a bere OPERATION AMOTEKUN, ni eyi ti o wa lati awon ipinle Yoruba, lati maa kun awon eso ati awon ologun lowo lati gbogun ti awon ajinigbe ati awon to n diha mora wa pa awon eniyan, ti won si tun n dana sun ile ati ohun ini won..

Awon Hausa ni ko si ohun to joo, won ni eto aabo ile Yoruba de ju ti oke oya lo. Awon Hausa tun hale mo ile Yoruba, won ni ti a ba ti duro ti amotekun, ki a gbagbe ipo Aare ni odun 2023.

Eyi mu ki awon ipinle ile Yoruba lo tun ero won pa. Awon araye towo bo Asiwaju Bola Tinubu lenu lati mo ibi ti o fi si, afi igba ti o fi ogbon agba da si oro naa. Ijoba apapo naa ni ajo naa ko tele ofin.


Amotekun ko tii tan nile ti ede aiyede Godwin Obaseki tii se gomina ipinle Edo ati alaga patapata egbe oselu APC tun fi gbona miiran yo, awon mesan-an kan ni woodu re ni awon yoo legbe oselu APC. Eyi naa da ise sile fun awon amofin ati awon agbejoro. Awon kan ni omi ti tan leyin eja re niyen, awon kan ni awon to yoo ti kere ju lati yo olori patapata fun egbe ni Naijiria. Bi ile-ejo kan se n daa pe won le yoo ni awon kan n daa pe ko see yo.


Inu ejo yii la wa ti arun kogboogun CORONAVIRUS tun gba ehinkule yo. Arakunrin omo orileede Italy lo wa fun ipade eto oro aje kan ni Ewekoro ni ipinle Ogun.

Arakunrin naa ni arun naa, eyi mu ki ikede lera-lera bere pe gbogbo eni to ba arakunrin naa wo baluu wo orileede yii ati awon ti won jo wo moto lo ilu Ewekoro pelu awon ti won jo se ipade okoowo naa yoju ni ile-iwosan fun ayewo. Ara Italy yii lo n gba itoju lowo ti omo Naijiria kan naa fi koo lara awon to ni asepo pelu re.

Eni to kan lo mo, aisan buruku yi ti fere run orile aye. O ti mu iyawo Aare orileede kan, o ti mu olori orileede kan, o ti pa oga ologun ibi kan, o ti ko lu opo awon agbaboolu to lowo lowo ni agbaye, o ti pa olori egbe agbaboolu ibi kan, o ti fere run awon orileede kan.


Arun yii ti buruke ni orileede Naijiria bayii, agbara ti fere maa kaa mo. Awon eleto ilera ni ki a ma se foya. Won ni ki a le kun un ni imototo. Awon aladura ni aisan ajoji ni, ko si nii pe lo. Ase Edumare. Ofin ki a fara mole ti bere, gbogbo ileewe ti wa ni titi pa, awon ileese ijoba ti fere lole tan.
Aisan buruku yii ni ko je ki abala ede aiyede Sanusi ati Ganduje pe rara.

Lamido Sanusi ni Emir ilu Kano nigba ti Abdullahi Gaduje je gomina ipinle naa. Bi Gaduje se yo Sanusi bayii ni ere ori itage miiran tun bere. Awon lobaloba ati loyeloye ba tun bere si n wo ki Sanusi. Awon gomina naa n wo loo ki, abule AWE to de si naa ni awon ko le gbagbe kiakia okiki ti o mu ba abule naa.


Arun coronavirus ko je ki a pe lori re rara. Arun naa ti di ki “olori o di ori re mu, ida n jo were”. “Oba mewaa igba mewaa ni ile aye yii”. Arun naa ti so eni ti a n sare lo yo mo di eni a n sa fun. Ti eniyan ba sese ti ilu oyinbo de, teru tomo nii fo mo won lorun, sugbon bayii, ere tete ni araye n sa ti e ba gbo pe enikan sese de ni eyikeyi ilu oyinbo.

O le debi wi pe ti eniyan ba ni ore to gbe eniyan lo si papako ofurufu, ore naa di eni ti a n sa fun. Aisan kata tabi ofinkin ko gbodo se eniyan bayii, eni naa di afunrasi loju ese. Arun ti won n gbe baba sa pamo fun omo, arun to n gbe omo sa fun baba, bee naa lo n keyin oko si aya.

Arun to so gomina di eni a ti mo yara, ti a wa n yoju woo lookan nitori pe o bowo lasan. Ki Eledua jowo ba wa dawo aburu duro.

Main

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...