Home / Àṣà Oòduà / Peter Fatomilola ní àìsí ẹ̀kọ́ ń mú káwọn òṣèré tíátà ó máá ṣe oun tí kò tọ́

Peter Fatomilola ní àìsí ẹ̀kọ́ ń mú káwọn òṣèré tíátà ó máá ṣe oun tí kò tọ́

Ṣé Yorùbá bọ̀ wọ́n ní báyé bá tojú àgbà bàjẹ́, àìmọ̀wàáhù wọn ní. Èyí ló díá fún bí àwọn tọ́rọ̀ kàn lágboolé òṣèré e tíátà se ń lọgun tantan pé,láyé ọjọ́sí, eré ìtàgé jẹ́ gbajúgbajà láwùjọ àwọn onítíátà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n léré tíátà ló sì ti ń pariwo pé eku kò ké bí eku mọ́ lórí ipa tí tíátà ń kó lórí ìdàgbàsókè àwùjọ.

Alàgbà Peter Fátómilọ́lá, ọ̀kàn lára àwọn òdú eléré tíátà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, t’óun pẹ̀lú kópa lásìkò eré ìtàgé ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ àti ìbí tí ọ̀rọ̀ ti wọ́ wá.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu