Home / Àṣà Oòduà / Ewi Toni: Atoto arere

Ewi Toni: Atoto arere

Gbogbo omo Yoruba
Ki gbogbo eye igbo pa lolo
Etu to n numo lowo
O ma lee numo
Gbogbo Ekulu ko ma lee numo loka
Omo Ade ti de to fe korin ogbon
Akewi Imoran de to fe farofo sasaro Imoran
Ki lo de?
To fi je wi pe eba omi lalakan n gbe?
A ni ki lo de tAlakan ko lori rara?
Odi n sunkun ailee soro
Aro n sukun airese rin,
Gbogbo omo Yoruba?
Adiye n sukun aileyin
Ajanaku n sunkun airete bo tie
Ebe la n b’Edumare
ko ma sewa lakotileta omo
Omo Yoruba?
ki lo de taa gbe goolu tore tan
Taa wa toro irin nile àro?
ki lo de taa gbasa a wa ta tan
Taa wa yansa ninu asa?
ka ma puro
ka ma seke rara,
Asa ni Yoruba sa ninu amu asa
E je ka fa’un a ni mora
kaye wa ohun ti ko sonu kiri
Asa alasa lo wa dohun kari
Bi eni ti n ta worobo
Omo Yoruba?
Kaye gbe Kete omi leri
ka maa polowo Yangan
Akewi imoran,
Omo Ade,
Eni balo lo ba ku
Soki lobe oge
Abo oro la so fun omoluabi
To ba denu re
Yoo dìsàkò.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Ewi Toni: Egbe APC iba oooo

Egbe ofo Toko coronal wo Nigeria Egbe abamo ti ki tele ofin. Akuse egbe tin pin rice agolo Kan fun eniyan mewa