Home / Iroyin Pajawiri / Ìpèníjà Baba Sùwé bè̩rè̩ nígbà tó pàdánù O̩mo̩ladun rè̩
babasuwe

Ìpèníjà Baba Sùwé bè̩rè̩ nígbà tó pàdánù O̩mo̩ladun rè̩

Yínká Àlàbí
Yoruba bo̩, wo̩n ni “aisan lo se e wo, a ko ri ti o̩lo̩jo̩ se”. Ko ki n se iroyin mo̩ pe iku ti poju gbajugbaja osere ori itage de ni o̩jo̩ aje o̩se̩ yii. Agba osere yii fi o̩mo̩ me̩ta saye lo̩ nigba ti o̩po̩ o̩mo̩o̩mo̩ naa wa nile̩. Ohun ibanuje̩ miiran tun ni pe oloogbe naa tun fi mama saye lo̩.


Iwadii fi idi re̩ mule̩ pe ge̩re̩ ti baba suwe padanu Omoladun aya re̩ ni nnkan ko ti se deedee fun mo̩. Koda, okiki re̩ ja wale̩ nitori awuyewuye to ro̩ mo̩ iku Omoladun naa. Le̩yin ti eleyii waye ni o̩dun 2009 ni awo̩n ajo̩ NDLEA naa tun fi o̩wo̩ sinkun ofin mu Alagba Babatunde Omidina yii kan naa pe o se daruke oogun oloro. O̩jo̩ me̩rinlelogun ni Alaga yii lo ni ahamo̩ wo̩n nitori pe Baba suwe ni oun ko gbe oogun oloro sugbo̩n awo̩n ajo̩ yii ni oogun wa ni ara re̩.

Le̩yin o̩jo̩ me̩rinlelogun yii ni Agbejoro Baba Suwe, Oloogbe Bamidele Aturu gba Baba yii sile̩ lo̩wo̩ wo̩n pe ko si bi oogun se fe̩ wa lara re̩ ki o ma ti yaa jade lati igba to ti wa ni ahamo̩ wo̩n. O̩dun 2011 ni awo̩n ajo̩ yii gbena woju Oloogbe naa.

O̩dun yii naa ni Baba Suwe pe e̩jo̩ ibaniloruko̩ je̩, ti ile-e̩jo̩ si ni ki ajo̩ NDLEA san milionu naira me̩e̩do̩gbo̩n fun baba Suwe sugbo̩n ti oloogbe yii ko ri gba ki O̩lo̩jo̩ to de. Papako ofurufu ti Muritala Mohammed ni wo̩n ti mu Alagba naa.
Le̩yin eleyii ni awo̩n aisan lorisiirisii be̩re̩ si ni jade lara re̩.


Nigba ti idaamu yii po̩ ni Arabinrin Esther Ajayi to je oludasile ile ijo̩sin kan gbe milionu me̩waa sile̩ fun ito̩ju baba Suwe, Igbakeji Aare̩ orileede yii, O̩jo̩gbo̩n Yemi Osinbajo naa fi milionu naira kan kun un. Kia ni awo̩n ajo̩ elere ori itage TAMPAN ti Alagba Bolaji Amusan je Aare̩ wo̩n ti wo̩n si ti n se itoju Baba Suwe lati igba ti aisan naa ti be̩re̩ gbe eto ati irinajo naa ko̩ Ogbeni Gbenga Adewusi lo̩run ti wo̩n si gbe Baba Suwe lo̩ si Rhode Island ni orileede Amerika.


Ni igba aye oloogbe yii, wo̩n se o̩po̩lo̩po̩ ere ori itage be̩e̩ ni o si gba ami e̩ye̩ lorisiirisii ki iku to poju re̩ de ni o̩mo̩ o̩dun me̩talelo̩go̩ta. Ki Eledua ba wa te̩ Babatunde Omidina si afe̩fe̩ ‘re.

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*