Home / Àṣà Oòduà / Igbákejì gómìnà Ọyọ ní Ladọja ṣe bẹbẹ lẹ́ka ètò ẹkọ́

Igbákejì gómìnà Ọyọ ní Ladọja ṣe bẹbẹ lẹ́ka ètò ẹkọ́

Igbákejì gómìnà Ọyọ ní Ladọja ṣe bẹbẹ lẹ́ka ètò ẹkọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé ìgbésẹ̀ òhun ìhùwàsí oníkálùkù láàyè, ìtàn ló ń kọ lóké eèpẹ̀.
Tẹbi tara tọ̀rẹ̀ àti àwọn èèkan nísẹ́ Ìjọba ló péjú láti ṣé ajọyọ̀ ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bí ọdún karundinlọgọrin gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Oloye Rashidi Adewọlu Ladọja.
Ayẹyẹ náà ti o waye ni gbọngan nla igbalejo ile itura ‘Premier Hotel’ ilu Ibadan l’ọ́jọ́ Ajé, jẹ ọ̀kan lara àkànṣe ètò tó waye níbi ifilọlẹ iwe ètò ẹ̀kọ́ nípa ìtàn àti ipò adarí tí aya gomina tẹ́lẹ̀rí náà, Arabinrin Bukọla Ladọja kọ fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó ń bẹ lorilẹede yìí.
Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ Onimọẹrọ Rauf Ọlaniyan, ti o ṣojú u Ìjọba ipinlẹ Ọyọ níbi ipejọpọ náà, gbósùba káre fún Olóyè Rashidi Ladọja fún iṣẹ́ takuntakun tí ó ṣe fún idagbasoke ipinlẹ Ọyọ, lásìkò iṣejọba rẹ gẹ́gẹ́ bí i gomina, paapaa jùlọ lẹka ètò ẹ̀kọ́ .
Ọlaniyan tẹsiwaju wí pé, ibi tí ọrọ ètò ẹ̀kọ́ ti wọ́ ní ẹkùn iwọ-oorun ni Ladọja mójútó lásìkò ìṣèjọba rẹ̀, kí ó tó di pé àwọn tí ó gba Ìjọba lọ́wọ́ rẹ̀ da ètò náà rú.
Ó fi kún ọrọ rẹ pé, Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ ń tọrọ ẹ̀mi gígùn àti àlàáfíà fún baba ọlọ́jọ́ ìbí, Kọmísánà fún ètò ẹ̀kọ́ àti ìmọ ìjìnlẹ̀ nipinlẹ Ọyọ,
Ọjọgbọn Kehinde Sangodoyin,nínú ọrọ rẹ̀, sapejuwe Olóyè Ladọja gẹ́gẹ́ bíi bàbá gidi. Ó ní láti ìgbà tí gomina tẹ́lẹ̀rí náà ti ń díje du ipò ni òun tí mọ ọ

Ó tẹ̀síwájú wí pé Ladọja jẹ ẹni tí ó máa ń fẹ́ kí nǹkan rere ti akata rẹ̀ jade wá, bẹẹ sì ni ó máa ń fẹ́ kí gbogbo èèyàn ṣe dáa dáa, bakan náà ló ní ó jẹ ẹnikan tí kìí bẹru, eyi si jẹ nǹkan pàtàkì tó yẹ kí gbogbo èèyàn ṣe awokọṣe rẹ̀.
Nínú ọrọ ti ẹ̀. arabinrin Bukọla Ladọja ṣàlàyé pé ipa ribiribi tí Olóyè Ladọja kó fún ìdàgbàsókè ètò ẹ̀kọ́ lásìkò iṣejọba rẹ̀, ló mú kí wọ́n ṣe ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bí náà mọ ifilọlẹ ìwé tuntun tí aya gomina tẹ́lẹ̀rí náà kọ.
Arabinrin Bukọla wá parọwa si Oloye Ladọja láti tẹsiwaju nínú iṣẹ́ rere, paàpá julọ lẹka ètò ẹ̀kọ́.

Nínú ọrọ idupẹ rẹ, Oloye Rashidi Ladọja dupẹ lọwọ gbogbo àwọn arirebaniṣe pẹ̀lú adura pé ohun rere ko ni tan lọdẹdẹ ẹnikẹni.
Ladọja sàlàyé pé, lara àwọn ìredi ti idagbasoke ètò ẹkọ fi jẹ oun logun ni wi pe òun gan ti jẹ anfani eto ẹkọ ọfẹ sẹyin, bẹẹ si ni òun mọ òhun tí ó tumọ si fun akẹkọọ láti joko sile nitori aisan owo ile ẹkọ
Gomina tẹ́lẹ̀rí náà fi kun ọrọ rẹ̀ pé, lára ohun tí ó yẹ kí Ìjọba tó ń bẹ lóde tẹsiwaju láti máa ṣe, ni itọju àwọn olùkọ́ nipasẹ sisan owó oṣu wọn lásìkò.

Ó ní òun kò ni dẹkun láti máa kopa nínú idagbasoke ètò ẹ̀kọ́ láwùjọ, bó ti wu kí ara di ara àgbà tó .


Ọ̀kan ò jọkan orin ni wọ́n fi dá àwọn àlejò lára yá níbi ayẹyẹ náà.
Lára àwọn èèyàn tí ó tún wà nikalẹ ni Ọjọgbọn Bọlanle Awe, adarí àwọn òṣìṣẹ́ gomina ipinlẹ Ọyọ, Oloye Bisi Ilaka, akọwe ijọba ipinlẹ Ọyọ, Arabinrin Olubamiwo Adeoṣun, àwọn lẹgbẹlẹgbẹ loyeloye àti bẹ́ẹ bẹẹ lọ.

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...