Home / Àṣà Oòduà / Àyájọ́ ‘Má wọ kọ́mú’

Àyájọ́ ‘Má wọ kọ́mú’

Àyájọ́ ‘Má wọ kọ́mú’ ló kò yìí, kín làkíyèsí ẹ̀yin obìnrin lórí àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Kẹwàá ọdọọdún ni àyájọ́ ọjọ́ ‘Má wọ kọ́mú’ lorilẹede Nàìjíríà eyi tó ń sọ fún àwọn obìnrin láti bá kọ́mú yan odì lọ́jọ́ náà.


Gẹ́gẹ́ báa ṣe mọ̀ oṣù Kẹwàá yìí kan náà ní àwùjọ àgbáyé yà sọ́tọ̀ fún àyájọ́ gbígbógun ti àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn, lọ́wọ́-lọ́wọ́ báyìí, orí ayélujára ti kún fún àwòrán awọ̀n obìnrin tó ń yan kọ́mú lódì lónìí láti dènà àrùn jẹjẹrẹ ọyàn.
Gẹ́gẹ́ báa se gbọ́, ohun tó fa ìdàsílẹ̀ àyájọ́ ọjọ́ ‘Má wọ kọ́mú ‘ ní Nàìjíríà ni láti pe àkíyèsíi àwọn obìnrin sí àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn àti àwọn ọ̀nà tí wọ́n le è gbà dènà rẹ̀.


Lásìkò àyájọ́ ọjọ́ ‘Má wọ kọ́mú’ yìí si ọpọ obìnrin máa ń fi ọyàn ọn wọn sílẹ̀ bí Ọlọ́run se dáa, láì wọ kọ́mú táa téèbó pè ní “Bra tabi Brassiere” lati kó o sókè, nítorí pé ìwádìí kan ti fìdíi rẹ̀ múlẹ̀ pe àwọ̀jù kọ́mú gan an máa ń fàìsàn jẹjẹrẹ.


Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tó ti ní àìsàn jẹjẹrẹ, tí orí ti kó yọ, ni kò le è ṣe láì wọ kọ́mú nítorí wọ́n nílò láti fi kọ́mú gbé fùkẹ̀ fùkẹ̀ sókè, eyi tí wọ́n se rọ́pò ọmú fún wọn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fi gé ọyàn wọn kúrò.


Díẹ̀ pàtàkì àyájọ́ ‘Má wọ kọ́mú’ fáwọn obìnrin Nàìjíríà nìyí:
Ọjọ́ ‘Má wọ kọ́mú ‘ yìí ló ń sètò ìtanijí fáwọn obìnrin nípa àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn, nítorí a gbọ pé kọ́mú àwọjù gan an le fa àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn.
Ọjọ́ yìí ni wọ́n tún fi máa ń sètò ìkówójọ fún iṣẹ́ ìwádì í láti gbógun ti àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn

Bákan náà tún ni ọjọ́ yìí wà láti rán àwọn obìnrin létí pé kí wọ́n lọ se àyẹ̀wò ọyàn wọn aìímọ̀ àìsàn jẹjẹrẹ ti le bá wọn lálejò láìmọ̀
Ọjọ́ yìí yóò tún jẹ kí àwọn obinrin tí wọ́n bá tètè kẹ́ẹ́fín àìsàn jẹjẹrẹ lara wọn lásìkò àyẹ̀wò le tètè rí ìtọ́jú gbà láti ká ọwọ́jà ọsẹ́ àìsàn náà kò.


Bẹ́ẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ kan ṣe kókó láti tètè paná àn àisan jẹjẹrẹ ọyàn . Àkọ́kọ́ ni síse àyẹ̀wò ọyàn obìnrin lóòrè kóòrè , paàpá ní ẹ̀ẹ̀kan lósù kan, ìgbà tó sì dára jùlọ láti se àyẹ̀wò ọyàn ni ọjọ́ Kẹwàá lẹ́yìn tí obìnrin bá parí nǹkan oṣù rẹ̀.

Àsìkò tí a ń se àyẹ̀wò ọyàn lósoosù kò gbọdọ̀ yàtọ, ó sì gbọdọ̀ bára dọ́gba eyi tí yóò se Ìrànlọ́wọ́ láti tètè rí èsì àyẹ̀wò tó dájú.
Àwọn obìnrin tí kò bá se nǹkan oṣù gbọdọ̀ mú ọjọ́ kan lósoosù tí wọn yóò máa se àyẹ̀wò ọyàn wọn.

Lásìkò àyẹ̀wò osoosù yìí, onítọ̀ùn yóò mọ bí ọyàn rẹ̀ se tóbi sí, bó se se múlọ́-múlọ́ sí àti bí awọ rẹ̀ se rí, èyi tí yóò jẹ́ kó tètè mọ̀ bí àyípadà kan bá dé sára ọyàn rẹ̀
Tónítọ̀ùn bá lọ ṣe àyẹ̀wò àgọ́ ara rẹ̀ nílé i ìwòsàn, ó gbọdọ̀ ri daju pe awọn osisẹ eleto ilera se ayẹwo ọyan fun oun lọna to peye, ti ẹnikọọkan si gbọdọ mọ baa ti se ayẹwo ọyan funra ẹni

Nibayii ti ayajọ ọjọ ‘Ma wọ kọmu’ tun ko báyìí, a n rọ gbogbo obinrin lati se àyẹ̀wò ọyàn wọn nítorí ijafara léwu, àti òkèrè ni oloju jinjin ti n mu ẹkun sun.

iroyinowuro

About ayangalu

x

Check Also

Èsì àyẹ̀wò tuntun Nàìjíríà fihàn pé “313” èèyàn ti gbàlejò Kofi 19 …àjọ NCDC

Èsì àyẹ̀wò tuntun Nàìjíríà fihàn pé “313” èèyàn ti gbàlejò Kofi 19 …àjọ NCDC À fi kí á bẹ Ọlọ́run kó bá wa dásí ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn ajániláyà pàtì yìí, bí àwọn tó ní kòrónáfairọ̀ọ̀sì ní Nàìjíríà ti ń peléke sí i báyìí,lẹ́yìn tí àjọ NCDC tún kéde okòólélọ́ọ̀dúnrún dín méje èèyàn tí èsì àyẹ̀wò wọn sẹ̀sẹ̀ jáde. Ní báyìí, èèyàn ẹgbẹ̀rún méje, àti . òjìlélẹ́gbẹ̀rin dínkan (7839) ni àkọsílẹ̀ wà pé ó ti ní àrùn náà ní Nàìjíríà. Àkójọpọ̀ ...