Home / Àṣà Oòduà / Kùkùlajà Ètò Ààbò, Gani Adams Ní OPC Àtàwọn Míì Ṣetán Láti Ṣiṣẹ́ Pẹ̀lú Àwọn Òṣìṣẹ́ Elétò Ààbò Nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá)

Kùkùlajà Ètò Ààbò, Gani Adams Ní OPC Àtàwọn Míì Ṣetán Láti Ṣiṣẹ́ Pẹ̀lú Àwọn Òṣìṣẹ́ Elétò Ààbò Nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá)

Kùkùlajà ètò ààbò,Gani Adams ní OPC àtàwọn míì ṣetán láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá)
Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé Oòduà (Yorùbá) bọ̀ wọ́n ní ọmọ onílùú kìí fẹ́ ò tú.
Gbogbo áwọn àgbààgbà nínú ẹgbẹ́ ajìjàgbara ẹgbẹ́ OPC àti Àgbẹ́kọ̀yà àtàwọn irú ẹgbẹ́ bẹ́ẹ̀ káàkiri ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) ní àwọn ti gbaradì báyìí láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò káàkiri ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá).
Ààrẹ Gani Adams tó jẹ́ olórí OPC tilẹ̀ sọ pé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ Oòduà (Yorùbá) làwọn ń retí láti sètò ìgbésẹ̀ ètò ààbò tó mọ́yán lórí tí àwọn pe orúkọ rẹ́ ní Operation Àmọ̀tẹ́kùn”.

Àkànṣe ètò ààbò yìí ni ìròyìn sọ pé ó jẹ́ àjọmọ̀ àti àjọrò gbogbo Gómìnà ní ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) lójúnà àti pèsè ètò ààbò tó péye fún mùtú mùwà káàkiri ilẹ̀ náà.
Èrò àwọn Gómìnà yìí ló dá lórí bí ìjínigbé àti ìpànìyàn ṣe wọ́pọ̀ ní ẹkùn náà tí wọ́n sì gbèrò láti mú òpin débá ìwà burúkú bẹ́ẹ̀.
Ṣé ní nǹkan bíi oṣù Kẹwàá ọdún yìí ni wọ́n gbèrò láti kó ìmọ̀ náà jáde bí ọmọ tuntun.
Ààrẹ Gani Adams ṣàlàyé síwájú síi pé ”Operation Àmọ̀tẹ́kùn” wà láti ṣèkúnwọ́ fún àwọn àjọ ààbò káàkiri ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá).
Àwọn àgbáríjọ ẹgbẹ́ tí wọ́n yóó lò ni ẹgbẹ́ OPC, Àgbẹ́kọ̀yà, Fijilanté, àtàwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) àti ọlọ́de káàkiri ìletò.

Àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí ti wá gbà láti ṣiṣẹ́ papọ̀ bẹ́ẹ̀ wọ́n ti kọ̀wé sí gbogbo Gómìnà, àtàwọn olórí elétò ààbò káàkiri ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá).
Àgbáríjọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ yìí ni wọ́n tí ṣe púpọ̀ ìpàdé ní ìlú Eko tí wọn yóó sì tún ṣe ní ìlú Ibadan , tíí ṣe Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní Ọjọ́rú ọ̀sẹ̀ yìí.

Ó ní kò sí bí ọ̀rọ̀ ètò ààbò yóó ṣe ṣeéṣe láì sí àwọn irinṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ tó dájú. Ó ní àwọn ọkọ̀ ti wà, àwọn ọlọ́pàá sì ti wà nílẹ̀ àṣẹ àwọn Ọlọ́pàá ni wọ́n ń dúró dè.
Ó ní nígbà tí kò ti sí Ìpínlẹ̀ kan lórílẹ̀-èdè yìí tó ní àṣẹ láti ra ohun ìjà olóró, tó sì jẹ́ pé àwọn Gómìnà ti setán láti ṣe gbogbo ohun àmúyẹ láti ra ohun tó bá kù.

Ó wá ṣàlàyé pé, kò tíì sí àrídájú pé bóyá ọkọ̀ òfurufú kékeré yóó wà lára ohun tí wọ́n fẹ́ lò ṣùgbọ́n pé Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ekiti ti ra ọkọ̀ bíi ogún sílẹ̀ fún ètò náà.
Alukoro fún Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ogun, Kunle Somorin ṣàlàyé pé Gómìnà kọ̀ọ̀kan ni yóó kó ọkọ̀ ọgọ́rùn sílẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ètò náà.

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...