Home / Àṣà Oòduà / Abọ ìwádìí yóó ṣọ pàtó ikú tó pàwọn òṣìṣẹ́ wa– Àjọ FRSC

Abọ ìwádìí yóó ṣọ pàtó ikú tó pàwọn òṣìṣẹ́ wa– Àjọ FRSC

Abọ ìwádìí yóó ṣọ pàtó ikú tó pàwọn òṣìṣẹ́ wa– Àjọ FRSC

Ìlú u gángan lọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ láyé,n Iàwọn àgbà se ṣọ pé,ẹ̀yìn ló kọ sẹ́nìkan, n tó kọjú sẹ́lòmíìn.
Bí a kò bá gbàgbé, àìpẹ́ yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ ajániláyà pàtì kan wáyé ní ìpínlẹ̀ Ògùn tí àwọn òǹwòye ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àṣà sí tí ṣọ ìgbésẹ̀ tó kàn nílànà ìbílẹ̀ fún àǹfààní ara a wọn.

Ọ̀rọ̀ yìí ni Adarí Àjọ tó ń rí sí ètò ìrìnnà ojú pópó, FRSC náà fèsì sí pé, àwọn kò leè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ààrá ló sán pa òṣìṣẹ́ àjò ọ̀hún mẹ́ta tó kú ní ìpínlẹ̀ Ògùn.

Adarí Àjọ FRSC ní ìpìńlẹ̀ náà, Ahmed Umar ló fi síta fún akọròyìn, pé ìgbésẹ̀ tó kàn ni láti mọ irú ikú tó pa àwọn òṣìṣẹ́ náà.

Umar ní òun tí àjọ náà mọ̀ ni pé iná ló ṣokùnfà rẹ̀, bóyá iná dédé gbé wọn ni tàbí ààrá ló sán pa wọ́n, àti pé nítorí náà ni àwọn ṣe bẹ̀rẹ̀ ìwádìí kíkún lórí rẹ̀.

Àmọ́, ó fikún-un pé, tí ìwádìí bá fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ààrá ló sán pa wọn, òun kò le è ṣe ẹbọ tàbí ṣe ètùtù nítorí ẹlẹ́ṣìn Mùsùlùmí ni òun, bẹ́ẹ̀ òun kò ti ẹ̀ gbàgbọ́ nínú rẹ̀.

Adarí Àjọ ẹ̀ṣọ́ ojú pópó FRSC nípìńlẹ̀ náà, Ahmed Umar wá fikún-un pé àwọn yóó fi ẹ̀rí ìwádìí àwọn léde fáyégbọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti parí ẹ̀ .

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...