Home / Àṣà Oòduà / Ṣeyi Makinde, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Sọ̀rọ̀ Lórí Àrùn Coronavirus Tó Ní

Ṣeyi Makinde, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Sọ̀rọ̀ Lórí Àrùn Coronavirus Tó Ní

Ìròyìn tó bá ọ̀pọ̀ lẹ́jafùú ni ìròyìn ‘Mo ti ní àrùn Coronavirus’ èyí tí Gómìnà Ṣèyí Mákindé gbé jáde ní ọjọ́ Ajé lójú òpó twitter rẹ̀.

Níbáyìí tí ó ti lo ọjọ́ méjì ní ìgbélé lẹ́yìn ìkéde yìí, gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé ti ṣàlàyé pé pẹ̀lú àánú Ọlọ́run, kò sí nǹkan tí Coronavirus leè fi òun àtàwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó ní àrùn náà ṣe.

Mákindé tó ní òun dúpẹ́ fún òbítíbitì òjò àdúrà tí gbogbo èèyàn ń fi ṣọwọ́ sí òun ṣàlàyé pé àdúrà náà ti ṣọ òun di bẹ́mìídíje , ẹ̀mí òun yi gírígírí, eléyìí tó fi ń dájú pé òun àti gbogbo àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ọ̀rọ̀ kan yóó rùú là.

Gómìnà Mákindé wá rọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà láti máa tẹ̀lé ìtọ́ni àti Ìlàkalẹ̀ Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá tí Ìjọba gbé kalẹ̀ láti gbógun ti àrùn COVID-19 ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti leè tètè kápá àrùn náà lọ́gán ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Níbáyìí, èèyàn mẹ́jọ ló ti kó àrùn Coronavirus ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nínú èyí tí Gómìnà Ṣèyí Mákindé pẹ̀lú wọn.

Bákan náà ni wọ́n ti tú èèyàn kan sílẹ̀ lẹ́yìn tí ó gba ìwòsàn lọ́wọ́ àrùn ọ̀hún.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

seun kuti

Orí kó Seun Kuti yọ kúrò lọ́wọ́ ikú ní yàrá ìgbàlejò US

Mary Fágbohùn Olórin Afrobeat Seun Kuti ti fi ìrírí ibanuje ọkàn rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà han nígbà tí ọta ibọn kan gúnlẹ̀ lójú fèrèsé yàrá igbalejo rẹ̀. O salaye ibapade to ba ni lẹru naa lori oju-iwe Instagram rẹ, o fi fidio ferese ti ọta ibọn naa bajẹ ati iho re han. Seun, ẹni ti o ṣalaye iyalẹnu, beere iwoye ti aabo ni Amẹrika. Ninu fonran naa, Seun Kuti sọ pe oun wa ninu yara igbalejo, ti oun n sinmi, ...