Home / Àṣà Oòduà / Adarí àgbà ilé ìwòsàn UCH kò ní àrùn Coronavirus mọ́

Adarí àgbà ilé ìwòsàn UCH kò ní àrùn Coronavirus mọ́

Họ́wùú! bí babaláwo bá ń kígbe ẹ̀fọ́rí, kín ni yóó jẹ́ àtubọtán aláìsàn? Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Adarí àgbà ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́, UCH Íbàdàn Ọ̀jọ̀gbọ́n Abiodun Otegbayo ti yiijẹ o, kò ní àrùn Coronavirus mọ́ lẹ́yìn tó sàyẹ̀wò àrùn náà nígbà kejì.

Ṣaájú ní Otegbayo ti kọ́ sàyẹ̀wò, tí èsì àyẹ̀wò ọ̀hún sì fi hàn pé ó ti fara káásá àrùn náà, èyí tó mú kó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún ìtọ́jú.

Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tó lo ọjọ́ mẹ́jọ ní ìyàsọ́tọ̀ ọ̀hún ló sàyẹ̀wò lẹ́ẹ̀kejì, tí èsì sì fi hàn pé kò ní àrùn náà lára mọ́.

Agbẹnusọ ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ UCH, Toye Akinrinlola ló fi ọ̀rọ̀ náà léde fún àwọn akọ̀rọ̀yìn lọ́jọ́bọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.