Home / Àṣà Oòduà / Ado Bayero di Emir Kano

Ado Bayero di Emir Kano

Adi Bayero di Emir Kano

Ìdààmú ilé ọlá kan kìí rọ̀, ko ko ko níí le. Ní báyìí Ìgbìmọ̀ ìsàkóso Ìjọba ìpínlẹ̀ Kano ti rọ Emir Sanusi lóyè ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹsàn án Oṣù kẹta ọdún 2020.

. Ó ti tó ọjọ́ mẹ́ta kan tí gbún-gbùn-gbún ti ń wáyé láàrin gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abdullahi Umar Ganduje àti Ẹmia Lamido Sanusi.

Akọ̀wé Ìjọba ìpínlẹ̀ Kano nínú àtẹ̀jáde kan ṣàlàyé pé ìgbìmọ̀ ìṣèjọba ìpínlẹ̀ náà yọ ọ́ lóyè lórí ẹ̀sùn pé ó ń tako àṣẹ tí gómìnà ìpínlẹ̀ náà ń pa.

Bákan náà ló ní lára àwọn ìwà títàpá sófin àti àṣẹ náà ni bí ó ṣe kọ láti farahàn láwọn ìpàdé àti ètò tí Ìjọba ìpínlẹ̀ náà bá gbé kalẹ̀ láìsí àwíjàre tó yanrantí.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni Mallam Sanusi ti tako àwọn àgbékalẹ̀ òfin tó de oyè jíjẹ ní ìpínlẹ̀ náà eléyìí tó ní yóó ba iyì ìlú Kano jẹ́ bí wọn kò bá mójútó o.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Kano ní àwọn gbé ìgbésẹ̀ láti yọ Sanusi nípò Ẹmia ìlú Kano láti dáàbò bo àṣà, ìṣẹ̀ṣe àti ẹ̀sìn tí ó mú iyì bá ìlú Kano.

Bí a kò bá gbàgbé, o dà bíìgbà tí ìtàn fẹ tún raarẹ kọ ní o, torí pé ìgbà kejì nìyí tí irúfẹ́ ìrọninípò bẹ́ẹ̀ yóó wáyé nínú ẹbí i Ẹmia yìí. Àkọ́kọ́ ni fànfà tó wáyé ní ọdún 1963 láàrin Sa Muhammadu Sanusi II kejì àti Ahmadu Bello , tí àwọn méjéèjì ti sílẹ̀ bora báyìí.

Gómìnà Ganduje ti ìpínlẹ̀ Kano wá ké sí àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ náà láti fọkànbalẹ̀ kí wọ́n sì máa bá iṣẹ́ òòjọ́ wọn lọ àti pé láìpẹ́ ni wọn yóó yan Ẹmia tuntun.
Bákan náà ní ìròyìn míì n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n tí yàn Aminu Ado Bayero rọ́pọ̀ Lamido Sanusi gẹ́gẹ́ bí Emir tuntun ìlú kano.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.