Home / Àṣà Oòduà / Ayé Kareem ti yí padà di òtun láti ìgbà tí ó ti ya àwòrán Ààre Macron- Alákoso rè ló so béè.

Ayé Kareem ti yí padà di òtun láti ìgbà tí ó ti ya àwòrán Ààre Macron- Alákoso rè ló so béè.

Óríre míràn ti to omo kékeré, omo odún mókànlá tí a mò sí Kareem Waris Olamilekan tí olórun fún ní èbùn kí ó ma ta nkan, ó ti ya ààre ilè Faransé tí a mò sí Ààre Emmanuel Macron, nígbà tí ó lo se àbèwò sí ojúbo Afrika tuntun ní ìlú Èkó.

Léyìn tí ó gba ilé ní owó Gómìnà ìpínlè Eko, ilé-ìfowópamó tí a mò sí Eko bank, ti towó bo ìwé láti gbà á tó lówó àwon òbí rè. Lára àwon èjé won ni wípé àwon yòó tó omo náà àti wípé àwon yóò ran lo sí ilé-èkó fún ogún odún(20 years).
Nínú ìfòrò wáni lénu wò tí won se fún alákoso Kareem tí a mò sí Adeniyi Adewole, ó jé kí ó di mímò wípé gbogbo ònà ni àwon n wá láti dábò bo ojó òla ayàwòrán omodé náà .
Ó so wípé inú òun dún púpò nítorí ilé-ìfówópamó ti Eco bank látàrí èjé tí won jé láti tójú omo náà. Ó so síwájú wípé sojú òun ni won se nígbá tí ó jé wípé òun ni Alákoso omo náà àti wípé won kò le se léyìn òun.

About Awo

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...