Home / Àṣà Oòduà / Ìròyìn Òrofó ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ìròyìn Òrofó ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

1 Ààrẹ Buhari yóò dé lónìí láti orílẹ̀ èdè China.

2 Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀ṣínbàjò gba àlejò àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọn gbé igbá orókè nínú ìdíje ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé.

3 Àwọn oníròyìn ń fi ìròyìn burúkú bá ìjọba Buhari jẹ́ – Alákòóso

4 Àwọn olùdíje ipò àarẹ nínú ẹgbẹ́ PDP yóò yọnu si ẹni ti o ba gbégbá orókè.

5 Mo ní ọgbọ́n ìṣèlú ju Buhari lọ – Turaki

6 Ìdìbò Ọ̀ṣun : Falae sọ ìdí tí àwọn olùdìbò ṣe gbọ́dọ̀ dìbò fún ẹgbẹ́ SDP yàtọ̀ di ẹgbẹ́ APC.

7 Oshiomole bẹnu àtẹ́ lu bí àwọn ọlọ́páà ṣe lọ tú ilé alàgbà Clark.

8 Ilé iṣẹ́ ọlọ́páà yọ àwọn ọlọ́páà tí wọn tú ilé alàgbà Edwin Clark.

9 Ilé iṣẹ́ ọlọ́páà gbé àwọn ẹni afurasí méjì-dín-lógún tí wọn dáná sun ilé iṣẹ́ ọlọ́páà ni ìlú Iwo lọ sí ilé ẹjọ́.

10 Ẹgbẹ́ APC ni Ìpínlẹ̀ Imo yóò lo ètò Ìdìbò gbangba-làṣá-ń-ta láti yan olùdíje gómìnà.

11 Àwọn olùdìbò mílíọ̀nù ó lè ní kò ì tíì wá gba káàdì Ìdìbò alálòpẹ́ ni Ìpínlẹ̀ Èkó – INEC.

12 Ẹgbẹ́ Ọdọ APC rọ àwọn ìgbìmọ́ kí wọn dín owó ìdíje kù.

13 Èrò bílíọ̀nù mẹ́rin ó lé ní bàálù gbé ní ọdún 2017 – IATA

14 Orílẹ̀ èdè India fọwọ́ sì kí ọkùnrin fẹ́ ọkùnrin gẹ́gẹ́ bí aya.

15 Orílẹ̀ èdè China yóò dá okoòwò tí ó lé ní tírílíọ̀nù méjì Náírà sí ilẹ̀ adúláwọ̀.

Ayé wa kò ní dàrú lágbára ELÉDÙMARÈ.. Àmín.

About Awo

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo