Home / Àṣà Oòduà / Èèyàn 627 ló lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Naijiria ní Ọjọ́ Ẹtì

Èèyàn 627 ló lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Naijiria ní Ọjọ́ Ẹtì

Èèyàn 627 ló lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Naijiria ní Ọjọ́ Ẹtì

Ẹgbẹ̀ta lé lọ́gbọ̀n o dín mẹta èèyàn (627 )tuntun míì ló ṣẹ̀sẹ̀ lùgbàdi àrùn Kofi -19 ní Nàìjíríà.

Àjọ tó ń rí sí ìdènà àti amójútó àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì, NCDC ló fi ìkéde náà síta lójú òpó abẹ́yefò Twitter rẹ̀.

Àpapọ̀ àwọn tó ti ní àrùn náà káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti wá di 15,181 báyìí.

Èèyàn 4,891 ló ti rí ìwòsàn gbà, nígbà tí àwọn 399 ti dèrò ọ̀run nípaṣẹ̀ àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ ọ̀hún.

Iye àwọn èèyàn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó àrùn náà ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan rèé:

Eko-229,FCT-65

Abia-54,Borno-42

Oyo-35,Rivers-28

Edo-28,Gombe-27

Ogun-21,Plateau-18

Delta-18,Bauchi-10

Kaduna-10,Benue-9

Ondo-8,Kwara-6

Nasarawa-4,Enugu-4

Sokoto-3,Niger-3

Kebbi-3,Yobe-1,Kano-1

Ìjọba lẹ́lẹ́kaǹka ń pàrọwà sí àwọn ọmọ Orílẹ̀ yìí láti ríi pé àdínkù bá ìtànkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kofi-19.

Bí ariwo ìkéde ṣé n lọ yìí, síbẹ̀ àwọn èèyàn kan nílẹ̀ yìí sí n yínmú pé irọ́ ni kò sí àrùn náà, àti pé, bí ó bá wà, ó yẹ kí wọ́n máa ṣàfíhàn àwọn èèyàn náà fún àwọn wò bíìran.
Ẹni ikú pa kò tó nǹkan, ẹni àìgbọ́n pa ló pọ̀.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

seun kuti

Orí kó Seun Kuti yọ kúrò lọ́wọ́ ikú ní yàrá ìgbàlejò US

Mary Fágbohùn Olórin Afrobeat Seun Kuti ti fi ìrírí ibanuje ọkàn rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà han nígbà tí ọta ibọn kan gúnlẹ̀ lójú fèrèsé yàrá igbalejo rẹ̀. O salaye ibapade to ba ni lẹru naa lori oju-iwe Instagram rẹ, o fi fidio ferese ti ọta ibọn naa bajẹ ati iho re han. Seun, ẹni ti o ṣalaye iyalẹnu, beere iwoye ti aabo ni Amẹrika. Ninu fonran naa, Seun Kuti sọ pe oun wa ninu yara igbalejo, ti oun n sinmi, ...