Home / Àṣà Oòduà / Èmi kò fé̩ràn láti máa fe̩nu ko obìnrin lé̩nu nínú eré – Taiwo Hassan

Èmi kò fé̩ràn láti máa fe̩nu ko obìnrin lé̩nu nínú eré – Taiwo Hassan

Taiwo Hassan Ọlọ́jọ́ọ̀bí, akọni òṣèré Yollywood tó dáńtọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Yoòbá bọ̀, wọ́n ní èèyàn tó bá monú-ún rò, ọpẹ́ ẹ rẹ̀ yóó lékún bóyá n ló fa sábàbí bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọ Nàìjíríà ti ń darapọ̀ kí àgbà òṣèré Taiwo Hassan kú oríire ọgọ́ta ọdún lórílẹ̀ eèpẹ̀ báyìí.

Yinka Quadri tó jẹ́ ọ̀rẹ́ tí wọ́n ti jọ ń ṣeré tipẹ́tipẹ́ náà kíi pé ọ̀rẹ́ to yatọ ni Ògògó jẹ́. A bí Taiwo Hassan tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Ògògó ní ọjọ́ , kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá, ọdún 1959. Ìlú Ilaro ní ìpínlẹ̀ Ogun ní gúúsù ìwọ oòrùn Nàìjíríà ni a ti bí Ògògó ọmọ Kúlúdò.

Òṣèré tí igba ojú mọ̀ ni Taiwo Hassan, ó ti ṣe àwọn eré tó lókìkí bíi Owo Blow, Sábàbí, Ìbínú elẹ́wọ́n, Atíìtẹ́bí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Odindin ọdún mẹ́tàlá ni Taiwo Hassan fi ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀ka tó ń mójútó omi ẹ̀rọ ní ìpínlẹ̀ Eko.

Ọdún 1994 ni Ògògó fẹ̀yìntì kúrò lẹ́nu iṣẹ́ Oba ìpínlẹ̀ Eko, kó tó gbájúmọ́ eré ṣíṣe ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Taiwo Hassan lọ sílé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Christ Church School nílùú Ilaro. Ó tún lọ sílé ìwé Yaba Technical College níbi tó ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ọkọ̀ títúnṣe.
Ògògó fẹ́ obìnrin méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Taiwo Hassan bí ọmọbìnrin mẹ́ta àti ọmọkùnrin kan.
Ọdún 1981 ni Taiwo Hassan bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ṣíṣe ní kété tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ Eko.

Ògògó ní ìdí tí òun fi ń dúró déédé bí ọmọkùnrin ni eré ìdárayá ẹ̀ṣẹ́ kíkàn tí òun gbádùn láti má a fi daraya.
Bákan náà ló tún ní òun fẹ́ràn láti máa gbọ́ orin paàpá ti àwọn ọdọ́ ìwóyí tó bá mọ́gbọ́n dání

Ògògó jẹ́ ọkùnrin tí ó ní àwọn ìwà kan tó sọ̀tọ̀ lágbo òṣèré.
Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan ló ti ṣàlàyé pé òun kìí fẹnuko obìnrin lẹ́nu nínú eré nítorí kò sí lára àdámọ́ òun.

Ògògó ní òun kò fi bẹẹ fẹ́ràn láti máa ṣe ipa olólùfẹ́ tó ń fi ìfẹ̀ han ní gbangba nínú eré àgbéléwò.

About ayangalu

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.