Home / Àṣà Oòduà / Fìdáù Ajímọ̀bi, ẹbí nìkan ní wọ́n ń retí–Ẹbí Ajímọ̀bi

Fìdáù Ajímọ̀bi, ẹbí nìkan ní wọ́n ń retí–Ẹbí Ajímọ̀bi

Fìdáù Ajímọ̀bi, ẹbí nìkan ní wọ́n ń retí–Ẹbí Ajímọ̀bi

Ṣé wọ́n ní kìí jẹ́ ti baba t’ọmọ, kó mọ́ ní ààlà. Èyí ló díá fún bí àwọn ẹbí olóògbé Abíọ́lá Ajímọ̀bi tí sàlàyé pé ,kí àwọn olùkẹ́dùn, ó má wulẹ̀ dààmu yọjú sí bi fìdáù, ní ìbámu pẹ̀lú n tí àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì n sọ , bí ó ti jẹ́ pé òní, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Keje, ni àdúrà ọjọ́ kẹjọ yóó wáyé fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀rí tó di olóògbé, Sẹ́nétọ̀ Isiaka Abíọ́lá Ajímọ̀bi.

Ètò àdúrà náà, Fìdáù, wà ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àti ìṣẹ ẹ̀sìn Islam. Ìdílé olóògbé sọ nínú Ìkéde tó fi síta fún ètò àdúrà náà pé, ẹbí Ajímọ̀bi nìkan ni ètò àdúrà náà wà fún, nítorí òfin tó rọ̀ mọ́ ìtànkálẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Ṣùgbọ́n ṣá, wọ́n ní àwọn aráàlú yóó ní àǹfààní láti wo bí ètò àdúrà náà bá ṣe ń lọ lórí amóhùnmáwòrán àti lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Ọjọ́ kẹẹdọgbọn, oṣù Kẹfà, ọdún 2020, ni Abíọ́lá Ajímọ̀bi kú, síléèwòsàn First Cardiologist, tó wà nílùú Èkó, lẹ́yìn tó ní àrùn Kofi-19.

Ẹni àádọ́rin ọdún olóògbé Abíọ́lá Ajímọ̀bi ko tó tẹ́rí gbaṣọ.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo