Home / Àṣà Oòduà / Ìdájọ́ ikú kò pọ̀jù fún gbogbo afipá bánilòpọ̀ – Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn

Ìdájọ́ ikú kò pọ̀jù fún gbogbo afipá bánilòpọ̀ – Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn

Ìdájọ́ ikú kò pọ̀jù fún gbogbo afipá bánilòpọ̀ – Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn

Àgbáríjọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọmọnìyàn bíi mẹ́rìnlà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti korò ojú sí ìwà ìfipábánilòpọ̀ àti ìṣekúpani tí àwọn obìnrin ń kojú láwùjọ.

Nínú ìpàdé àwọn oníròyìn tó wáyé lópin ọ̀sẹ̀ yìí nílùú Ìbàdàn, àwọn ẹgbẹ́ náà gbarata lórí ìwà ọ̀daràn tí àwọn amòòkùnṣèkà kan ń hù sí ọmọdé àti àwọn àgbà tó jẹ́ obìnrin, paàpá jùlọ lórí ọ̀rọ̀ ìṣekúpani àti ìfipábánilòpọ̀.

Ọ̀kan lára àwọn aṣojú ẹgbẹ́ náà, Arábìnrin Grace Oluwatoye késí ìjọba àti àwọn agbófinró láti bójútó wàhálà tí àwọn ọmọbìnrin ń dojúkọ lásìkò yìí.

Ó ní àwọn ọmọbìnrin bíi mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó pàdánù ẹ̀mí wọn nítorí ìfipábánilòpọ̀ àti ìwà ipá láàrin ọ̀sẹ̀ kan ti fa àìbalẹ̀ ọkàn fún gbogbo abiyamọ pátá.

Oluwatoye ní ohun tó ń kọnilóminú ni pé àwọn obìnrin tó jẹ́ pé láti ara wọn ni gbogbo ènìyàn ti jáde náà lótún wá ń kojú irú wàhálà báyìí. Gbogbo eléyìí kò sì ṣẹ̀yìn ètò ààbò tó mẹ́hẹ láwùjọ.

Ó ní àìfi ẹnìkan kan jófin lórílẹ̀ yìí ló fàá tí àwọn olubi ẹ̀dá náà fi ń tẹ̀síwájú nínú ìwà ọ̀daràn. Ìgbàgbọ́ ẹgbẹ́ náà ni pé ìgbésẹ̀ láti dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ náà yóó yá kánkán tí ìjọba bá bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìdájọ́ ikú fún ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá gbámú.

Àwọn ẹgbẹ́ náà tún fi ẹ̀sùn kan àwọn obìnrin tó ń ta ọtí líle àti pàrágà pé àwọn náà lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ìfipábánilòpọ̀ yìí nítorí pé gbogbo nǹkan burúkú tí àwọn ọ̀daràn náà ń mu ló ń fún wọn ní ìgboyà láti ṣiṣẹ́ ibi. Wọ́n ní “ẹni tí kò mu ọtí líle kò ní bá ọmọ ọdún mẹ́rin sí mẹ́jọ sùn”.

Wọ́n ké sí Ìjọba láti rí sí ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin tó ń ta pàrágà láwùjọ kí àdínkù le dé bá ipá búburú tí ìmukúmu ń kó láàrin wa.

Lára ohun tí wọ́n tún késí ìjọba láti ṣe kí ìwà ọ̀daràn náà le káṣẹ̀ nílẹ̀ ní àgbékalẹ̀ òfin tí yóó máa dá sẹ̀ríà fún àwọn afipábánilòpọ̀, àti ìbáwí tó péye fún gbogbo ẹni tí ajé ìwà ìbàjẹ́ bá ṣí mọ́ lórí.

Arábìnrin Oluwatoye tún rọ àwọn onílé iṣẹ́ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ láti máa fi ààyè ìlanilọ́yẹ̀ sílẹ̀ lórí àwọn ètò tí wọ́n ń ṣe, kí òye túbọ̀ lé è yé àwọn ará ilé síi lórí àwọn ewu tó rọ̀ mọ́ ìfipábánilòpọ̀ àti ìṣekúpani láwùjọ wa.

Ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tó jẹ́ aṣojú ẹgbẹ́ náà, Arákùnrin Hamzat Kọlawọle ṣọ pé ìwà tí kò bójúmu tí kò sì yẹ àwùjọ ni ìwà ìfipábánilòpọ̀.

Ó ní ọkùnrin tó bá fi ipá bá ọmọdé tàbí àgbàlagbà tó jẹ́ obìnrin lọ̀pọ̀ ti ṣe ohun burúkú.Kọlawọle ní kò yẹ kí á bí irú àwọn ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ sí ayé rárá dé ibi pé a ó máa pè wọ́n ní ọkùnrin.

Ó ní irú àwọn ọkùnrin tó ń hu irú ìwà ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ ló yẹ kí gbogbo àwọn ọkùnrin tó kù pawọ́pọ̀ láti báwí nítorí wọ́n ba gbogbo àwọn tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ lójú jẹ́.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...